Adìẹ KFC kò dùn mọ́n!

Adie KFC

Ẹkú ọjọ́ mẹ́ta o ẹ̀yin ènìà pàtàkì wọ̀nyí. Ṣe dáradára ni mo bá gbogbo yín o?
Ọ̀rọ̀ ọ t’òní á fẹ́ jọ yẹ̀yẹ́ létí ẹlòmíì, ṣùgbọ́n kìí ṣ’àwàdà rárá o. Ọ̀rọ̀ gidi ni.

Ẹ ní kílódé? Ẹ mà ṣeun o. Ebi ló pa mí ní ìrọ̀lẹ́ òní tó mún mi ya ilé oúnjẹ olókìkí nì tí wọ́n ń pè ní KFC. Adìẹ díndín ni wọ́n ń tà níbẹ̀. ‘Tapátẹsẹ̀ ni wọ́n ń dín in. Tí ẹ bá fẹ́ jẹ ẹ́ ní ẹyọ-ẹyọ, ẹ lè rà á bẹ́ẹ̀. Bó sì jẹ́ àdàpọ̀ ẹsẹ̀ àti apá lẹ fẹ́, ìyẹn náà wà. Kódà wọn a tún máa ṣè’kan pẹlẹbẹ láti igbá-àyà adìẹ, wọ́n á tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ sí ààrin búrẹ́dì pẹ̀lú ẹ̀fọ́ díẹ̀ àti àwọn midinmíìdìn ní ọlọ́kanòjọ̀kan. Àwọn olóyìnbó a máa pè’yẹn ní “Burger”. Kiní ọ̀hún a máa wù’yàn jẹ o jàre. Àgàgà àwọn tí wọ́n fi ata sí dáadáa. Wọ́n tún ṣe’kan tó jọ dùndú anọ̀mọ́ tí wọ́n ń pè ní “fries”. Kiní ọ̀hún a máa dùn tí wọ́n bá dín in gbẹ dáadáa. Parí-parí ẹ̀, ènìà tún lè fi ọtí ẹlẹ́ridòdò kan lé e. Gbogbo rẹ̀ á wá ṣe rẹ́gí-rẹ́gí l’ọ́nà ikùn. Ara olúwarẹ̀ a wá yá gágá.

Kí ló wá fa ẹjọ́ o Alákọ̀wé? Yó dára fún gbogbo yín o.

Ṣé ẹ rí adìẹ KFC yíì, wọn ò kàn kí ń dín in lásán o. Wọ́n á kọ́kọ́ fi àwọn èròjà kan pa á lára kí wọ́n to sọ ọ́ sínú agbada òróró gbígbóná. Àwọn èròjà wọ̀n-ọn nì ní wọ́n fún oújẹ wọn ní adùn tó dára dé ibi pé, wọ́n sọ ọ́ ní ‘àjẹ-lá-ìka’ – ajẹ́pé ení bá jẹ adìẹ díndín wọn, ńṣe ni olúwarẹ̀ á máa lá ìka tó fi mún adìẹ náà sẹ́nu nígbà tó bá jẹ ẹ́ tán. Nítorí ìdí èyí, KFC di gbajúgbajà, wọ́n di ọ̀kan nínú àwọn ilé-oúnjẹ aláràjẹ tó lókìkí jù ní gbogbo àgbáyé.

Tó bá jẹ́ lóòótọ́ ni àwọn èròjà náà dùn tó bẹ́ẹ̀, kí ló ṣe tí àwọn ilé-oúnjẹ ìyókù ò ṣe máa lò wọ́n se oúnjẹ tiwọn? Ìtàn ń bẹ níbẹ̀. Ṣé Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ‘bí kò bá ní ìdí, obìnrin ò kí ń jẹ́ Kúmólú’. Ìdí abájọ ni pé, gbogbo àwọn èròjà náà, àti ètò bí wọ́n ṣe ń pò wọ́ pọ̀, nǹkan àṣírí ńlá ni. Láti ọdún 1930 títí dé ọjó òní, awo ńlá ló jẹ́ láàrin wọn. Ẹnìkankan ò sì tí ì já wọn.

Àmọ́ ṣá o, ṣé bí a bá gbìyànjú títí, tí a kò rí kókó tú, a ó fi kókó ọ̀hún sílẹ̀, a ó wàá okùn míì lọ? Ìyẹn ló dífá fún àwọn aládìẹ díndín ‘yòókù, tí wọ́n dẹ́kun fífarawé KFC, tí wọ́n sì wá àwọn èròjà tiwọn lọ.

Ní tèmi o, mo ti jẹ adìẹ díndín níbòmíràn tọ́n dùn yùngbà dé’bi pé, ti KFC gangan ò dùn lẹ́nu mi mọ́n! Àgàgà lọ́dọ̀ àwọn ará Pakistan àti India. Wọn a máa fi ata sí oúnjẹ dáadáa bíi tiwa.

Lónìí, mo yà KFC lọ nítorí ebi ni. Mo ra itan àti igbá-àyà adìẹ, pẹ̀lú àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ oújẹ kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú ife Pepsi tútù kan. Bí mo ṣe bù ú jẹ ni adìẹ náà kàn ṣ’ọ̀rá sìnkìn sí mi lẹ́nu. Kiní ọ̀hún ò tiẹ̀ ta rárá, ó wá rí ràṣì-ràṣì lẹ́nu. Nígbà tó ṣe mí bí ẹní fẹ́ bì, mo bá tọ́ pepsi díẹ̀ sẹ́nu. Pepsi náà dàbí èyí tí wọ́n ti ṣí sílẹ̀ látààná, kò tiẹ̀ ru rárá – ó kàn dà bí omi lásán. Èsùrẹ́ sì fẹ́ gbé mi. Mo yáa mọ̀’wọ̀n ara mi, mo dìde kúrò ni ìkọ̀ oújẹ wọn, mo gba Pizza Express kan tí ń bẹ ní ẹ̀bá ibẹ̀ lọ. Mò bẹ̀ wọ́n kí wọ́n bá mi rẹ́ ata rodo sórí Pizza mi o jàre. Wọ́n kúkú ti dámi mọ̀n níbẹ̀ pé jata-jata ni mo jẹ́.

Pizza Yoruba

Èrò tèmi ni pé, bíótilẹ̀jẹ́pé ilé-iṣẹ́ KFC fi dá wa lójú pé àwọn ò tíì pààrọ̀ àwọn èròjà tí wọ́n ń fi s’óúnjẹ láti ọdún 1930, kiní ọ̀hún ò dùn lẹ́nu tèmi mọ́n o. Ó ṣeéṣe pé ahọ́n ọ̀n mi ló ti yí padà, nítorí lóòótọ́ ni kiní ọ̀hún dùn sí mi nígbà kan rí. Tàbí pé, irọ́ ni ilé-iṣẹ́ náà ń pa fún wa. Bí o ti wù kí ó rí, ẹ ò yó rí mi níbẹ̀ mọ́n láti òní lọ.

Ẹ̀yin ńkọ́? Ǹjẹ́ ẹ ti jẹun ní KFC láìpẹ́ yìí bí? Báwo lẹ ṣe rí oúnjẹ wọn sí? Ẹ jẹ́ ká gbọ́ o, ẹ fèsì kalẹ̀ o.

Toò, ó tún dìgbà kan ná o ẹ̀yin ẹ̀dá pàtàkì mi. Kí Olódùmarè dá wa sí o. Àṣe.

Advertisements

Èkó

Ẹ ǹlẹ́ o ẹ̀yin ẹ̀dá Ọlọ́run wọ̀nyí. Fún apá kẹfà Ìgbésí-ayé Alákọ̀wé, ẹ fìkàlẹ̀ lé e pẹ̀lú mi nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yìí. Ẹ jẹ́ ká dé Ìpínlẹ̀ Èkó, ká wòran díẹ̀.

Ní gbogbo ìgbà, èmi a kúkú máa kan sáárá sí gómìnà Èkó àná – Alàgbà Raji Faṣọla. Iṣẹ́ ńlá ló ṣe. Àyípadà tó dé bá ìpínlẹ̀ yìí ò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn rárá. Ó sì sọ Èkó di ibi àmúyangan – ibi iyì, ibi ẹ̀yẹ.

Nígbà kan rí, èmi ò kí ń fẹ́ rìn tí ilẹ̀ bá ti ṣú. Àmọ́ lóde òní, ẹ̀rù ò ṣábà á ba’ni mọ́n. Ọpẹ́ ni f’Ólúwa fún àwọn àyípadà rere wọ̀nyí. A ò ní ri àpadà sí burúkú láí-láí o. Kí gómìnà òní yáa múra síṣẹ́ gidi-gaan ni.

Ẹ ò jẹ́ ká dánu dúró ń’bẹ̀un bí? Wọ́n ní “ọ̀rọ̀ púpọ̀, irọ́ ní í mú wá”. Yoòbá káàbọ̀. A jẹ́ pé mo kí gbogbo yín kú ọdún titun o. Ọdúnnìí, á sàn wá s’ówó, sàn wá s’ọ́mọ, sàn wá sí àláfíà – tí í ṣe baálẹ̀ ọrọ̀.

Àṣẹ.

Agbègbè Waterloo

Alákọ̀wé mo tún dé. Ní apá karùn-ún Ìgbésí-ayé Alákọ̀wé, ẹ jẹ́ ká yà sí agbègbè Waterloo, létí bèbè gúsù odò Thames, ní olú-ìlú Igilàńdì wa yìí. Ibi tí ọdún Kérésì ti ń lọ ni kẹlẹlẹ.

Agbègbè yìí la ti lè rí ọ̀bìrìkìtì ńlá tí wọ́n ń pè ní ‘ojú Lọndọn’ – London Eye.

London Eye tí wọ́n kọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì ẹ̀yẹ ọdún kẹgbẹ̀rúnkejì – ìyẹn ọdún márùndínlógún sẹ́yìn báyìí. Èròngbà àwọn t’ọ́n kọ́ ọ síbẹ̀ ni pé kó kàn wà níbẹ̀ fún bí ọdún kan sí méjì. Ṣùgbọ́n lónìí ó ti di bàbàrà, oun àtọ́kasí ní ilú Lọndọn o. Tí ẹ bá dé’bẹ̀ ẹ ó rí ìdí abájọ. Èro tó tò kalẹ̀ pé àwọn fẹ́ gùn ún ò l’óǹkà. Bẹ́ẹ̀ owó ni gbogbo wọn ó san, kìí ṣe ọ̀fẹ́.

Onírúirú àwọn òṣèré ni wọ́n máa ń ṣeré l’óde ibẹ̀. Láti káàkiri àgbáyé sì ni wọ́n ti wá. Kódà láti Afirika pẹ̀lú.

Oúnjẹ náà wà ní ọlọ́kanòjọ̀kan, bótilẹ̀jẹ́pé ìjẹkújẹ oní ṣúgà la rí jẹ lọ́jọ́ náà. Ńṣe ni sẹ́lẹ̀ru ṣọkọléètì ń ṣàn bí omi níbẹ̀.

Toò, a tún ṣe t’òní o, ọpẹ́ ni fún Olódùmarè. Ìyókù tun di ẹ̀yìn ọdún ńlá. Kí Olúwa ṣọ́ wa jù’gbà náà lọ o.

Ódàbọ̀.

Afárá Lọndọn

Pàtàkì ni afárá yìí jẹ́ ní Lọndọn. Àwọn ará Róòmù ni wọ́n kọ́kọ́ kọ́ afárá náà ní nkan bi 2,000 ọdún sẹ́yìn. Látìgbà náà, wọ́n ti tún un kọ́ lẹ́ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Ẹ bámi dé agbègbè àyíká Lọndọn Bridge – ìgbádùn ń bẹ níbẹ̀. Níbi ìgbádùn bá sì wà, dandan ni kí ẹ bá èmi kinní yìí níbẹ̀ 🙂

Mo kí yín kú ìpalẹ̀mọ́ ọdún o. Ire owó, ire ọmọ, ire àláfíà tí í ṣe baálẹ̀ ọrọ̀.

Ódìgbà kan ná.

Abúlé Stratford

Apá keta ti bà bí àdàbà o. Ẹ bámi dé abúlé kan ní Lọndọn tí wọ́n ń pè ní Stratford. Ibẹ̀ ni ìdíje Olympics ti ṣẹlẹ̀ ní ìdun-ùnta, ìyẹn l’ọ́dún mẹ́ta sẹ́yìn.

Ire o!

Ilẹ̀-Ìyanu Ọ̀gìnìntìn

Ìgbésí ayé Alákọ̀wé apá kejì ti bọ́ o. Ẹ bá mi dé Ilẹ̀-Ìyanu Ọ̀gìnìntìn tí ń bẹ nínú ọgbà ńlá Hyde Park.

Ẹ má gbàgbé láti tẹ̀lé mi lórí YouTube o, kí n lè mọ̀n dájú pé ẹ ń gbádùn mi. Ṣé ẹ̀yin gbọ́rọ̀-gbọ́rọ̀ ni ọ̀gá àwa sọ̀rọ̀-sọ̀rọ̀.

Ẹṣeun púpọ̀ o.

Ààrin gbùngbùn Lọndọn

Ètò titun látọwọ́ Alákọ̀wé. N ó máa mú yín káàkiri ìlú yìí kí ẹ lè rí ìgbésí ayé ọmọ Yoòbá nílẹ̀ yìí. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ lètò náà ó máa wáyé lórí ìkànnì YouTube mi, tàbí ní alakowe.com.

Ètò kíní // Ìgbésí ayé Alákọ̀wé – Ààrin gbùngbùn Lọndọn // Ẹ bámi kálọ sí Piccadilly Circus, Leicester Square àti China Town.

Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Ajeju Suga

Ṣé mo sọ níjọ́sí pé ìfẹ́ àfẹ́jù tí ń bẹ láàrin ọmọ ènìyàn àti ṣúgà bímọ. Bẹ́ẹ̀ ni o. Kódà ọmọ tí wọ́n bí ju ẹyọ kan ṣoṣo lo. Àwọn ọmọ náà ni Ààrùn, Àìsàn, Àìlera àti Àárẹ̀.

Àwọn ọmọ wọ̀nyí a máa farahàn ní ìgbésí-ayé ẹ̀dá ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà àrà, wọn a sì máa da ọmọ-ènìyàn l’áàmú. Díẹ̀ nínú àwọn ọ̀nà àrà náà nìwọ̀nyí;

Ẹ̀jẹ̀ Ríru, Ìfúnpá Gíga, Ìtọ̀ Ṣúgà, Wárápá, Àìsàn Ọkàn, Ọpọlọ Wíwú, Ojú Fífọ́, Ìdákọ́lẹ, Àpọ̀jù Ọ̀rá-Ẹ̀jẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Abí ẹ kò rí i pé àjẹjù ṣúgà kò dára fún ọmọ ènìyàn rárá bí? Ó yẹ ká yẹra fún un nígbà gbogbo, kí ó má baà ṣe àkóbá fún wa.

Toò, ẹ jẹ́ ká fi man báhun lónìí nítorí pé “ṣókí l’ọbẹ̀ oge”. Èmi ni Alákọ̀wé yín ọ̀wọ́n. Ó tún dìgbà kan ná.

Ènìyàn àti Ṣúgà

Sibi Suga Yoruba
Yoòbá ò purọ́ nígbà tó wípé “a kìí fi oyin sẹ́nu ká tutọ́”. Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ni, ó sì nítumọ̀ púpọ̀. Àmọ́ bó ti nítumọ̀ ìjìnlẹ̀ náà ló ni ti eréfèé.

Àdídùn tí ń bẹ nínú oyin dára púpọ̀, ó sì kún nkan tí ara ẹni ń fẹ́. Ẹlẹ́dàá ló ṣe ètò oyin ṣíṣe, tí Ó sì fi fún kòkòrò abìyẹ́ nì láti máa ṣe.

Ní inú oje òdòdó ni kòkòrò oyin ti ń yọ àdídùn ṣe oyin. Nígbà tí mo wà ní kékeré, èmi àti ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi àti àwọn ọ̀rẹ́ wa máa ń fẹ́nu fa oje òdòdó mun. A máa dùn lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣé áńgẹ́lì ọmọdé ni kò jẹ́ ka pàdé èyí tó máa pa wá lára. Nígbà míràn gan-an ńṣe la máa kúkú sọ odidi òdòdó sẹ́nu kàló, tí a ó rún un lẹ́nu wọ̀mù-wọ̀mù, tí a ó sì gbé e mìn gbùn-ún, tí nkankan ò sì ní ṣe wá.

Ododo Yoruba
Bó ti wà láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé nìyẹn. Àwọn nkan tí Ẹlẹ́dàá ṣe, àwá ọmọ ènìyan pẹ̀lú, Ó ti fi ìbáṣepọ̀ sáàrin wa pé kí a jẹ́ aláànfàní arawa, kí a sì máa ṣe arawa lóore. Ìyẹn láàrin àwa ọmọ ènìyàn àti ẹranko gbogbo – ẹranko si ewéko, eweko sí ènìyàn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣùgbọ́n àwa ọmọ ènìyàn a kìí yé kọjá àyè wa. A ní ìrọwọ́-rọsẹ̀ tó ti wà láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àgbáyé yìí ò tẹ́ wa lọ́rùn o. A ní dandan àfi ká ṣe tí inú wa. A ní iṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ò dára tó, àfi ká tún un ṣe ní ìlànà tiwa. Àpẹrẹ ìwà yìí kan rèé;

Ẹ̀dá ọmọ ènìyàn kọ̀ ó ní oyin ò dùn tó o. Ó tún wípe rárá, ìrèké náà kù díẹ̀ káàtó. A ní àfí ká ṣe ìwádìí nkan tó fa adùn inú àwọn nkan wọ̀nyí, kí a lè ṣe wọ́n ní ìlànà tiwa.

Ọmọ ènìyàn bá fún omi inú ìrèké, ó gbé e raná ti omi náa fi gbẹ, tí ó fi ku kiní kan funfun báláhú. Kiní ọ̀hún jọ iyọ̀, àmọ́ dídùn rẹ̀ yàtọ̀ sí ti iyọ̀, ó jọ ti oyin àti ìrèké. Ẹ̀dá ọmọ ènìyàn ní “Kò tán bí!? A ti rí ìdí abájọ, ojú ti ẹ̀yin ọmọ kòkòrò!”.

Kokoro Oyin Cocacola Yoruba

Ọmọ ènìyàn wo kiní ọ̀hún títí ó ní “Ṣúgà la ó máa pè ọ́”

Ṣúgà amáyé dùn
Ìwọ ni gan-an ajẹmáleètu
Àdídù inú oyin abara funfun
Àní ìwọ gan-an lọ dùn jù
Ìwọ ni ìrèké gbóríyìn fún
Àwọ̀ àlà rẹ ń wọ̀ mí lójú

Kofi Yoruba Suga

Láti ìgbà yìí ni ọmọ èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ń tọ́ kiní funfun ọ̀hún sí gbogbo nkan jíjẹ àti mímu. Wọn a máa tọ́ ṣúgà sí omi. Wọn a máa tọ́ ọ sí ẹ̀kọ mímu. Kódà àwọn kan a máa lá a ní gbẹrẹfu.

Àwọn àgbàlagbà Yorùbá ti parí ọ̀rọ̀ tipẹ́-tipẹ́. Wọ́n ní “Àṣejù ni bábá àṣetẹ́”. Ọ̀rọ̀ àgbà rèé, kì báà pẹ́, a máa padà ṣẹ nígbẹ̀yìn ni. Nígbà tó yá, ifẹ́ àfẹ́jù tí ń bẹ láàrin ọmọ ènìyàn àti ṣúgà bá bímọ. Ìfẹ́ ọ̀hún ni àṣejù. Ọmọ náà ni àṣetẹ́.

Kí wá ló ṣẹlẹ̀? N ó fi tó o yín létí láìpẹ́. Ẹ padà wá gbọ́ àbọ̀ ọ̀rọ̀.

Ẹ ṣeun, mò ń bọ̀ ná.

Ìtẹ̀wé Yorùbá titun gbòde

Ẹ ǹlẹ́ o ẹ̀yin tèmi. Ó tójọ́ mẹ́ta kan. Ǹjẹ́ ẹ rántí ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta sẹ́hìn, mo ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí a lè gbà kọ èdè Yorùbá pẹ̀lú àmì lórí àwọn ẹ̀rọ wa.

Ọ̀nà titun kan ti balẹ̀ wàyí o! Yorubaname.com ni wọ́n fún wa ní ẹ̀bùn yí ní ọ̀fẹ́.

Mo ti ń ṣe àmúlò ìtẹ̀wé yìí ní kété tó jáde, kí n lè fún un yín lábọ̀ nípa rẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Bíótilẹ̀jẹ́pé ó ṣòro ó lò lákọ̀ọ́kọ́, nítorí kò mọ́n mi lára, kò pẹ́ náà tó fi mọ́nra. Kódà, òun ni mò ń lò lọ́wọ́ báyìí.

Díẹ̀ nínú àwọn àǹfàní tọ́n hàn sí mi nìwọ̀nyí:

1. Àyè àti fi àmì sí ‘n’ àti ‘m’ ( ǹ ń, m̀ ḿ )
2. Ó ń ṣiṣẹ́ lórí Windows àti Mac
3. Kò l’áàńsí lórí Ayélujára láti ṣiṣẹ́
4. Ó rọrùn láti lò púpọ̀ ju àwọn ìyókù lọ, tí ó bá ti móni lára tán.
5. Ọ̀fẹ́ ni!

Ajẹ́pé ẹ jẹ́ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Yorubaname.com fún akitiyan ńlá yìí. Ó dámi lójú pé èyí kò ní ṣe àṣemọn wọn o. Lágbára Èdùmàrè.