Ata ju ata lọ

Obe-Ata

Ẹ wá wo orí ológbò látẹ o ẹ̀yin èèyàn mi! “Èwo lẹ tún rí o Alákọ̀wé?” Yó yẹ yín kalẹ́! Mo mà tún rí nkan o.

Lóòótọ́ àwa ọmọ Nàìjá a fẹ́ran ata, àgàgà àwa ti ilẹ̀ Oòduà. Ẹlòmíì a se’bẹ̀, a fi ata já a. Kódà a rí ẹni tí kò ní jẹun kankan àfi tí ata bá wà níbẹ̀. Dájú-dájú ìran jata-jata ni àwa ń ṣe.

Òun ni mo fi ń yangàn fún àwọn ọ̀rẹ mi kan nílẹ̀ yìí o. Mo wí fún wọn pé kòsí oúnjẹ kankan nílẹ̀ wọn tó láta to tiwa. Mo tún ṣakọ pé irúfẹ́ ata tí èmi Alákọ̀wé ò lè jẹ – wọn kò tí ì ṣẹ̀dá ẹ̀ nílẹ̀ yìí.

Àwọn òyìnbó dá mi lóhùn pé òtítọ pọ́nbélé ni mo sọ, n kò parọ́ rárá.   Wọ́n tún wípé kódà àwọn aláwọ̀ funfun tí mo rí yìí – tí àwọn bá ṣèṣì jẹ irú ata tí a ń wí yìí, ńṣe ni ojú àwọn á di pípọ́n kuku bí aṣọ àparò! Bẹ́ẹ̀náàni gbogbo ọ̀nàfun á máa ta àwọn bí ẹní máa kú ni. Wọ́n ní nítorí ìdí èyí ni àwọn kò ṣe kí ń jẹ ata. Pé tí oúnjẹ bá ti láta fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ báyìí, àwọn a yáa yẹra fún un.  Mo rín ẹ̀rín àrínbomilójú nígbà tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yìí tán. Kání àwọn babańlá wa mọ̀n níjọ́ kìíní àná ni, bóyá àwọn Gẹ̀ẹ́sì ò bá tí múnwa sìn.

Mo bá tún mú ìpanu aláta kan tí mo múdání, mo sọ ọ́ sẹ́nu kàló, mo rún un lẹ́nu wómú-wómú. Ẹ̀rù ba àwọn ẹlẹgbẹ́ mi aláwọ̀funfun náà. Wọn gbóríyìn fún mi, wọ́n wa ń wo èmi Alákọ̀wé gẹ́gẹ́ bí òrìṣà kan láàrin wọn.

ata

Ní òjijì ni ẹnìkan bá dìde láàrin wọn. Ọmọ orílẹ̀èdè Ṣáínà ni onítọ̀hún ń ṣe. Jin ni orúkọ rẹ̀, èmi àti arákùrin náà sì ti mọ̀nrawa fún nkan bí ọdún kàn nípasẹ̀ iṣẹ́ òòjọ́ wa. Jin bá bọ̀ bí ẹní pòwe. Ó ní “ní ìlú afọ́jú, olójúkan ni ọba wọn”.

Ẹ gbà mí o! Ta wa ló fún ará Ṣáínà lẹ́nu ọ̀rọ̀? Èmi náà bá dá lóhùn pé njẹ́ ó mọ̀n pé ṣàkì kìí ṣẹgbẹ́ ọ̀rá bí? Mo nawọ́ ìpanu aláta tí mo ń jẹ sí i – “ó dáa náà gbà èyí kí o tọ́ ọ wò. Ṣé tí ogún ẹ̀ni bá dáni lójú a fi ń gbárí ni?”

Jin kúkú kọ̀ ó l’óun ò jẹ ìpanu aláta. Ó ní kékeré nìyẹn. Kàkà kí ó jẹ, òwe ló tún pa. Ó tẹnu bọ̀rọ̀ ó wí pé “Àìrìnjìnnà làìrí abuké ọ̀kẹ́rẹ́, tí a bá rìn jìnnà á ó rí abuké erin. N ó mú ìrẹ Alákọ̀wé dé ibi tí wọ́n ti ń jẹ ata gidi nílẹ̀ yìí, ìwọ yíò sì gba Ọlọ́run l’ọ́gàá! Ìwọ á gbà pé àti ṣàkì o, àti ọ̀rá o, ẹran abọ́dìí ni ọba gbogbo wọn”

Mo wí fún Jin pé tó bá rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́ kó nìṣó níbẹ̀. Mo fọwọ́ sọ̀yà pé irúkírú oúnjẹ alátá tí wọ́n bá sè fún mi níbẹ̀, èmi Alákọ̀wé á jẹ ẹ́ láì mu omi kankan sí i.

chilli_cool

Ẹbá ọ̀nà kékeré kan ní àdúgbò kọ́lọ́fín kan láàrìn gbùgbùn ilú Lọndọn ni ilé-oúnjẹ náà sápamọ́ sí.
Orúkọ rẹ̀ ni Chilli Cool. Orúkọ ọ̀hún sì fẹ́ dá’yà já’ni. Ata rodo ní ń jẹ́ Chilli. Àmọ́ ẹ̀rù ò b’odò, ibi líle làá ba ọkùnrin.

A wọlé a fi ìkàlẹ̀ lé e. Ìgbà náà ni Jin wí fún mi pé kí n má wùlẹ̀ wo ìwé-oúnjẹ́ tí wọn fún wa. Pé òun Jin ni yó yan gbogbo nkan tí màá jẹ. O ní ṣé mo rántí nkan tí mo sọ? “Tí ìwọ bá lè jẹun láì mu omi lóòótọ́, èmi Jin ọmọ ilẹ̀ Yiwu ní Ṣáínà ni yíò sanwó. Ṣùgbọ́n tí ìwọ Alákọ̀wé Yoòbá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ajẹ́pé mo rí oúnjẹ ọ̀fẹ́ jẹ nìyẹn nítorí ìwọ ni wàá tọwọ́ bọ àpò o”. Èmi náà bá dá a lóhùn pé mo fara mọ́n ọn bẹ́ẹ̀. “Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, oun tó bá yá kìí tún pẹ́ mọ́n, oúnjẹ ọ̀hún dà? Ẹ gbé e jáde kí n máa báṣẹ́ lọ jàre!”

Obe-Ata-Adie

Obe-Ata-2

Nígbà tó yá ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ń gbóòórùn nkan tó ń tasánsán bí ọbẹ̀ ata. Kíà ni wọ́n bá gbé àwọn oúnjẹ ọ̀hún wá lọ́kọ̀ọ̀kan. Ni nkan bá ṣe!

Ẹ wá wo ata ní onírúirú, ọlọ́kanòjọ̀kan àti oríṣìíríṣìí! Gbogbo irúfẹ́ ata tí Olódùmarè dá sí ilé-ayé ni wọ́n péjọ sínú àwo. Gbogbo wọn wá ń játùbú nínú omi ata, wọ́n ṣe àwọ̀ kàlákìní.

Obe-Ata-3

ounje-ata

Ẹ̀rù Ọlọ́run sì bà mí. Oúnjẹ rèé àbí àtẹ aláta? Jin rẹ́rìn-ín músẹ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í jẹun lọ. “Óyá Alákọ̀wé oúnjẹ yá, àbí bóo ni?” Mo kúkú gbìyànjú ẹ̀. Mo fi ṣíbí tọ́ díẹ̀ sẹ́nu, ni òógùn bá bò mí, ahọ́n mi ṣe bí ẹní fẹ́ bó.

“Omí o!”

Advertisements

Pàtàkì Ìwé Kíkọ Àti Kíkà Ní Èdè Abínibí

Ogboju-ode-ninu-igbo-irunmole
Oun tí a ní là ń náání. Àwọn àgbà Yorùbá ni wọ́n wí bẹ́ẹ̀. Njẹ́ ní òde òni àwa ọmọ Odùduwà ń náání oun tiwa bí? Ọ̀rọ̀ ọ́ pọ̀ níbẹ̀ o ẹ̀yin ará mi. Ó dáa ẹ jẹ́ ká mú’kan níbẹ̀ ká gbé e yẹ̀wò.

Bíótilẹ̀jẹ́pé ọ̀pọ̀ ni kò fẹ́ràn láti máa sọ èdè Yorùbá lẹ́nu mọ́n, dájú-dájú púpọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí gbọ́ ọ l’ágbọ̀ọ́yé, wọn kò kàn kí ń sọ ọ́ ni.

Lára àwọn agbọ́másọ wọ̀nyí, bóyá la lè rí ìkankan nínú wọn tó mọn èdè Yorùbá kà dáradára, ká tilẹ̀ má sọ̀rọ̀ ọ kíkọ. Àgàgà tí a bá fi àmì sọ́rọ̀, a máa fa ìrújú fún púpọ̀ nínú wọn. Ó mú mi rántí nkan tí ẹnìkan wí lóri Twitter níjọ́sí. Ó ní Yorùbá kíkọ̀ èmi Alákọ̀wé fẹ́ jọ èdè Lárúbáwá lójú òun nítorí àwọn àmì ọ̀rọ̀ tí mo máa ń fi sí i. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún pa mí ní ẹ̀rin lọ́jọ́ náà kì í ṣe díẹ̀.

Àmọ́ ọ̀rọ̀ burúkú òhun ẹ̀rín kọ́ rèé ni ẹ̀yin èèyàn mi? À á ti wá gbọ́? Ṣé ẹ rí ibi tí ọmọ Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí nípà èdè Gẹ̀ẹ́sì kíkọ? Ótì o! Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀. Àbí ẹ rí ibi tí ọmọ Ilẹ̀ Faransé ti ń ránmú sọ Faransé bí? Èmi ò rí i rí o.

Ogboju-Ode
Kí ló wá fà á? Ìkíní ni pé l’óòótọ́ a kò ní ètò ìkọ̀wésílẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá kí àwọn Lárúbáwá àti àwọn ará Úróòpù tó dé. Ajẹ́pé kò sí nínú àṣà wa láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Àtẹnudẹ́nu àtìrandéran ni àwá ń ṣe ní àtètèkọ́ṣe. Ṣùgbọ́n ayé àtijọ́ nìyẹn o. Ayé ń lọ, à ń tọ̀ ọ́ ni. Èdè Yorùbá ti di kíkọsílẹ̀ ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn aṣíwájú èdè káàkiri Afirika nípa kíkọsílẹ̀.

Ìkejì ni pé àwa ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ Káàárọ̀oòjíire ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ pátápátá. Kódà, àfi bí ẹni pé ẹlòmíràn kórira èdè abínibí tirẹ̀ gan-an ni. Nítorí ìdí èyí a kì í ṣe àmúlò èdè Yorùbá fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ile-ìwé wa, tàbí fún ìjírórò l’áwùjọ òṣèlú, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Yorùbá ń parun lọ kọ́ yìí? Àbí kí ni ọ̀nà àbáyọ? Àwọ̀n àgbà Gẹ̀ẹ́sì bọ̀ wọ́n ní “Ìrìnàjò ńlá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbésẹ̀ kan ṣoṣo”. Gẹ̀ẹ́sì káàbọ̀ o jàre. Ọgbọ́n àgbà ń bẹ lọ́dọ̀ tiwọn náà. Ajẹ́pé Yoòbá gbọ́n Èèbó gbọ́n ni wọ́n fi dá ilẹ̀ London 🙂

Yoruba-Twitter
Ká tiẹ̀ pa àwàdà tì. Kíni irúfẹ́ ìgbésẹ̀ kíní tó bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò ńlá ìsọ́jí èdè Yorùbá kíkọ àti kíkà? Toò, ìyẹn dọwọ́ olúkúlùkù wa. Láyé òde òní gbogbo wa ni ònkọ̀wé níwọ̀n ara tiwa. Yálà lórí ẹ̀rọ ojútáyé nì tí a mọ̀n sí Facebook, tàbí àwùjọ ẹjọ́wẹ́wẹ́ nì tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Twitter. Kíní ṣe tí àwa ò máa ṣe àmúlò èdè wa lórí àwọn àwùjọ wọ̀nyí déédé. Lóòótọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì ló pabambarì káàkiri àgbàyé, àmọ́ a láti gbé èdè tiwa náà lárugẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ibòmíràn ṣe máa ń ṣe.

Toò, ọ̀rọ̀ mi ò jù báyìí lọ. Ṣé wọ́n ní “ọ̀rọ̀ púpọ̀, irọ́ ní í mú wá” Tó tó ṣe bí òwe. Ìpàdé wa bí oyin o.

Alakowe.com

alakowe-dot-com

Alákọ̀wé ti gba òmìnira kúro ní WordPress.org 🙂 Ẹ súré tete lọ sí www.alakowe.com

Ire o!

Ebola

Kokoro_Ebola
Mo kí gbogbo yín o. Ẹ kú ọjọ́ mẹ́ta. Ẹ sì kú àìfaraálẹ̀ náà. Olúwa yó máa fúnwa ní alékún okun àti agbára o.

Toò, ọ̀rọ̀ ló kó mokó morò wá. Èé ti rí? Ọ̀rọ̀ Ebola yìí mà ni o. Kòkòrò búburú tí í fa àjàkálẹ̀ ààrùn. Kòkòrò tí kò gbóògùn.

Bóo la ti wá fẹ́ ṣe é o? Ibo là á gbe gbà? Àwọn oní Bókobòko níwá, Èbólà lẹ́hìn. Àfi kí Elédùà kówa yọ.

Àmọ́ ṣá, Yoòbá ti wípé ojú l’alákàn fi ń ṣọ́rí. Kí oníkálukú yáa tẹra mọ́n ètò ìmọ́ntótó rẹ̀. Kí ó sì máa ṣe àkíyèsí gbogbo nkan tí ń lọ ní’tòsí.

Orísìírísìí là ń gbọ́ nípa kí la lè ṣe láti dáàbò bo’ra ẹni. Àwọn kan ní omi gbígbóná àti iyọ̀ ni ká fi wẹ̀. Kíá ni àti mùsùlùmí àti kìrìstẹ́nì ń da omígbóná ságbárí. A tún gbọ́ pé orógbó tàbí obì ni àjẹsára tọ́n lè báni yẹra fún ààrùn Ebola. Wéré ni tọ́mọ́ndé tàgbà ń rún orógbó lẹ́nu bí i gúgúrú, tí wọ́n sì ń jẹ obì bí ẹní jẹ̀pà. Àt’orógbó àt’obì o, wọn ò ṣé rà lọ́jà mọ́n, ńṣe ni wọ́n gbówó lérí tete.

Bẹ́ẹ̀ rèé ènìyàn ò báà bẹ́ sínú àmù ọmígbóná oníyọ̀, kó jẹ́ orógbó agbọ̀n kan, kó sì jẹ obì tó kún apẹ̀rẹ̀. Tí olúwarẹ̀ bá ko Ebola, tí kò bá ṣe àfira wá nkan ṣe, ṣàngbà fọ́ nìyẹn – ó di gbére.

Èmi wí tèmi, àmọ́ ẹnu ọlọ́rọ̀ lọ̀rọ̀ ti ń dùn. Ẹ fetí sí ètò Yorùbá Gbòde níbi tí olóòtú Ṣọla Yusuf ti gba amòye onímọ̀ nípa Ebola, tí wọ́n sì làwá lọ́yẹ̀ dáadáa.

Ẹ máa ṣe pẹ̀lẹ́-pẹ̀lẹ́ o. Ìpàdé wa bí oyin o. Ire o.

Igbó Funfun – Apá kẹta Ìrìnkèrindò Moravia

Igbo_funfun_alakowe

Mo kúkú tẹnu mọ́n ọn pé Oníyanu ni Ọlọ́run. Nípa ìṣẹ̀dá ọmọ ènìyàn, Ó ṣ’èkan ní dúdú aró, ọ̀kan funfun gbòò bí aṣọ àlà. Ẹlòmíì a pọ́n kuku bí aṣọ àparò, Elédùà ló ní kó máa rí bẹ́ẹ̀.

Njẹ́ Aṣèyíṣèmíì ni Ọlọ́run. Nípa ìṣẹ̀dá igi inú igbó, Ọba Lókè tún dá a bí àrà ọ̀tọ̀. Èyí tó kúrú, èyí tó ga, gbogbo wọn n’ọ́n péjọ sínú igbo, tí wọn ń jẹ́rìí sí agbára Ẹlẹ́dàá wọn. Òmíì fífẹ̀ gbàràgàdà bí igi osè tó tan gbòngbò kálẹ̀ káàkiri. Àwọn wọ̀nyí kìí ṣábàá ga lọ títí. Yoòbá bọ̀ ó ni “Ẹni bá máa ga, ẹsẹ̀ rẹ̀ yó tínrín” èyí ló dífá fún igi ọ̀pẹ́ nínú igbó. Ẹ jẹ́ ká fi ìyẹn sílẹ̀ ná.

Alákọ̀wé Yorùbá, ẹni Olú Ọ̀run dá lọ́lá, mo dé ibi igbó nì tí wọ́n ń pè ní Igbó Funfun. Mo rí iṣẹ́ Ọlọ́run Ọba.

Ẹ ní kíni mo rí? Yó yẹ yín o. Ní ọ̀nà àbáwọ igbó náà, àwọn arúgbó igi tò síbẹ̀ wàlàhìhì. Ìtàn fi yé wa pé àwọn igi náà ti wà níbẹ̀ láti ayé-báyé ni. Àwọ̀ wọn jẹ́ funfun nini, wọn kò sì ní ewé kankan lórí rárá. Wọ́n ní àwọn igi náà ti wà níbẹ̀ fún bíi ọgọ́rùn-ún mélòóka ọdún. Àgbà igi gbáà ni wọ́n.

Igbo_funfun

Igi funfun eléyìí ní tirẹ̀ mọn’rarẹ̀ lágbà. Kò ṣèṣe adìẹ funfun o. Bí atẹ́gùn ṣe ń fẹ́ ni àwọn igi náà ń fì sọ́tùn-ún sósì pẹ̀lú ẹ̀lẹ̀. Ṣé pẹ̀lẹ́-pẹ̀lẹ́ ni ìṣe àgbà, òun ni ijó ọba. Bẹ́ẹ̀ náà ni nkan tó jọ ohùn kẹ́lẹ́-kẹ́lẹ́ a máa ti ọ̀dọ̀ àwọn igi náà wá. Á wá dàbí pé wọ́n ń kíni káàbọ̀ sí inú igbó àwọn.

Tí èèyàn bá kọ́kọ́ wọnú igbó náà, yó rí àpẹrẹ pé ọkọ̀ a máa rin ọ̀nà tó wọnú igbó náà lọ. Ọ̀nà náà tẹ́jú pẹrẹsẹ, ó sì wọnú igbó náà lọ tààrà. Àmì ìkìlọ̀ kan ń bẹ níbẹ̀ tó wípe “Ìwọ máṣẹ yà kúrò lójú ọ̀ná yìí títí tí ìwọ yó ṣe tọ igbó yìí já o!”. Èyí ṣẹ̀rù bani díẹ̀. Mo yáa tẹsẹ̀ mọ́nrìn ní tèmi, èmi adúláwọ̀ tòótọ́ 🙂

ona_inu_igbo_alakowe

Lọ́gán tí mo wọnú igbó náà ni mo ṣàkíyèsí i pé àwọn igi ibẹ̀ ti pàwọ̀dà, wọn kò jẹ́ funfun mọ́n. Wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í léwé kọ̀ọ̀kan lára, bíótilẹ̀jẹ́pé irúfẹ́ igi kannáà ni àwọn pẹ̀lú àwọn funfun ti iwájú igbó náà. Ìdí ẹ̀ ni pé àwọn igi abẹwélórí wọ̀nyí ò tíì di arúgbó igi. Ojọ́-orí àwọn igi wònyí ò tíì ju nkan bíi ọgọ́rùn-ún kan ọdún lọ. A jẹ́ pé àwọn ò tíì pá lórí, wọn kò tíì h’ewú lára. Àṣé ìṣe ènìyà náà ni ìṣe igi níbìkan. Ọlọ́run tóbi.

Nígbà tó yá mo bá tún dé ibìkan tó dàbí ilẹ̀ olókùúta bákan. Àwọn igi tó hù níbẹ̀, ńṣẹ ni gbòngbò wọn lọ́pọ̀ mọ́n òkúta. Ọ̀kan ló tiẹ̀ ṣemí bí ẹ̀rín bí ẹ̀rù o. Lábẹ́ igi kan, ilẹ̀ ṣe bí orí ènìyàn kan tó lanu bí ẹní kọrin. Ó kọ́kọ́ bàmí lẹ́rù ná, ṣùgbọ́n ó tún pamí ní ẹ̀rín nígbà tó múnmi rántí orin tí olóòtú ètò Tiwa’n’tiwa Alàgbà Oyèkúnlé Azeez máa ń kọ lẹ́ẹ̀kọ̀kan. “♫ òkúta òde, gbòngbò òde, ♪ ẹ bùnwa lóde lò ò..♫

Ile_lanu_alakowe

Ẹ̀rín náà ni mò ń rín tí mo fi tọ igbó náà já sí pápá kan. Bí mo ti jáde ni mò rí àwọn ẹranko méjì kan tí wọn jọ irúfẹ́ ẹṣin kan. Èyí ló fi mí lọ́kàn balẹ̀ gbáà pé ibi a wí la dé yìí o. Oko àgbẹ̀ tí mo dé tì ni mo já sí lágá. Ọlọ́run ló bámi ṣé kìí ṣèèyàn.

awon_esin_alakowe

Bí arákùnrin àgbẹ̀ náa ti rí mi ló súré tete tọ̀ mí wá, a wá jọ pasẹ̀pọ̀ dé ibi abà rẹ̀. Ajá rẹ̀ náà ń gbọ̀nrù tẹ̀lé wa. A kí arawa ní èdè wọn. Ṣé ẹ mọ̀n pé èmí kinni yìí agbédè-gbẹ́yọ̀ ni mí. Olúmọ̀nọ́nrìn náà ni mí pẹ̀lú. Gbàrà tí a wọ abà náà ni oúnjẹ́ ṣetán àti jẹ. Ṣé Yorùbá ti kúkú ní “a kìí lẹ́ni ní mọsàn ká mun kíkan’. Orí Yoòbá ti pé tipẹ́ o jàre 🙂

ounje_alakowe

Ẹ ṣeun o ẹ̀yin ènìyàn rere wọ̀nyí. Ẹ kú àtìlẹ́hìn mi. Olúwa á gbé yín ga o. Tí ẹ bá gbádùn àwọn ìtàn mi, ẹ má ṣàìfi èsì sílẹ̀ fún mi.
Tàbí kí ẹ tẹ̀lé mí ní @alakoweyoruba [Twitter]
Bẹ́ẹ̀ náà ẹ lè fìwé ránṣẹ́ sí mi ní alakoweyoruba@gmail.com

Ẹ padà wá láìpẹ́ fún àwọn àròkọ kan t’ọ́n ń bọ̀ lọ́nà. Nkan ń bẹ ẹ̀yin ọmọ ènìyàn!

Yàrá Inú Òfurufú – àpá kejì Ìrìnkèrindò Moravia

Àwámárìídìí ni Ọlọ́run Ọba. Ẹlẹ́dàá tó dá ayé òun ọ̀run. Alágbára ńlá tó dá àwa ọmọ ènìyàn sórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àgbáyé. Òun náà ló tẹ́ òfurufú léwa lórí. Olódùmarè ló pa á láṣẹ fún òbìrìkìtì ayé kó máa yí oòrùn po láìdúró. Kí ìyípo kan máa jẹ́ ọdún kan. Àní sẹ́, Elédùà Apàṣẹwàá ló ní kí ayé gan-an máa pòyì ararẹ̀. Kí ìpòyì kan máa jẹ́ ọjọ́ kan. Àsẹ Ẹlẹ́dàá ni.

Èdùmàrè tó dá ẹ̀dá ọmọ èèyàn tó pàṣẹ pé ká máa bí síi ká sì máa rẹ̀ síi, Òun náa ló ṣe ọpọlọ ọmọ ènìyàn yàtọ̀ sí ti ẹranko lásán. Ó wípé bí ọjọ́ ṣe ń yí lé ọjọ́, tí oṣù ń yí l’óṣù, tí ọdún yí l’ọ́dún, kí ọpọlọ wá náà máa gbòòrò síi. Àlékún ọgbọ́n, àlékún ìmọ̀, àlékún òye ọmọ ènìyàn láti ìrandéran ti mú ìlọsíwájú kànkà bá àwa ọmọ ènìyàn gbáà. Ẹ̀yà ẹranko kan kò jẹ́ rí àwa ọmọ ènìyàn fín, àyàfi tó bá ń wa àbùkù òun ìparun. Àwa ẹ̀dá ọmọ aráyé, a wá dúró gẹ́gẹ́ bí kábiíòsí láàrin gbogbo àwọn ẹ̀dá tí Olódùmarè dá sí ilé-ayé.

Olódùmarè gbàwá láàyè yìí ká máa dárà bó ti wù wá ní ilé ayé. Kódà àgbára àti làákáyè àwá ọmọ ènìyàn ti gá dé’bi pé àwọn mìíran a máa sọ pé kòsí Ọlọrun, pé àwa gan-an là ń bẹ ní ìdí orò. A ṣe títí a kọ́lé gíga roro bí ẹni pé kí àwa ọmọ ènìyàn gan-an lọ máa fi ojú-ọ̀run ṣe ibùgbé. Ṣèbí àwa gangan ni ẹlẹ́dàá?

Ṣùgbọ́n o, Ṣèyíówùú Ọlọ́run kìí ṣe àìfagbára rẹ̀ han ọmọ ènìyàn lẹ́kọ̀kan. Njẹ́ ìwọ kọ́le gíga sókè réré? Kú iṣẹ́ ńlá ìwọ ọmọ ènìyàn, kú u làálàá. Èmi Olódùmarè ma sì rọ òjò lé e, ma fẹ́ ẹ̀fúùfùlẹ̀lẹ̀ lé e, ma fi ìkúùkù òjò bò ó mọ́nlẹ̀, ma ṣán an ní àrá ṣààràrà, bẹ́ẹ̀ náà ma sì fa òṣùmàrè pálapàla sí iwájú rẹ̀. Ma ṣe gbogbo èyí láàrin ìṣẹ́jú kan péré.

Nígbàtí ìwọ Alákọ̀wé bá gbójú wòkè wo ilé gogoro ńlá nì, tí ìwọ ń gbóríyìn fún àwọn ọmọ ènìyàn tí wọ́n kọ́ irúfẹ́ ilé àràmàndà yìí, tí o rò pé nkan ìyanu ni, Èmi Ẹlẹ́dàá rẹ̀, N ó tan ìmọ́nlẹ̀ oòrùn lókè, tí ògo tirẹ̀ yíò borí ògo ilé gogoro náà, tí ìwọ yíò sì mọ̀n dájú pé Tèmi ni iyì gbogbo, Tèmi ni ìyanu, nítorí agbára Tèmi ju ti ọmọ ènìyàn lọ. Ìwọ Alákọ̀wé ti mo fi èdè Yoòbá ta lọ́rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn, o yíò mọ̀n pé Èmi Olódùmarè ni Ẹlẹ́dàá gbogbo nkan.

Bí gbogbo rẹ̀ se ṣẹlẹ̀ gan-an lẹ gbọ́ ní ṣókí yẹn. Nígbàtí mo dé iwájú ilé gogoro náà, tí mo rí bó ṣe ga tó, kàkà kí n yin ọmọ ènìyàn, Elédùà ni mo kí kú iṣẹ́ ìyanu.

DSCF0073

Toò, Yoòbá ní oun tó bá yá kìí tún pẹ́ mọ́n. Kíákíá mo darapọ̀ mọ́n àwọn èrò níbẹ̀, a bẹ̀rẹ̀ sí í gun àwọn pẹ̀tẹ́ẹ̀sì lọ́kọ̀kan láti àbáwọlé ilé náà títí dé yàrá ńlá kan. Níbẹ̀ ni àwọn èrò ti tò láti gun àkàsọ̀ afẹ̀rọfà tí ń gbéni lọ sókè nítorí ilé ọ̀hún ga tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, kò ṣé fẹsẹ̀ lásán gùn dé òkè. Nígbàtí a dé òkè tán, yàrá ńlá mìíràn la tún bọ́ sí. Yàrá náà ni àwọn fèrèsé fífẹ̀ tọ́n fúnni láàfàní láti wo ìta. Ìran tí gbogbo wá fẹ́ wò náà nìyẹn, nítorí láti ibẹ̀ ènìyàn á máa wo ilẹ̀ lókèrè. Gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń rìn nílẹ̀ á wa dàbí i kòkòrò kékèké.

DSCF0106

Àmọ́n kò tán níbẹ̀ o. Ó tún ṣeéṣe láti lọ sókè síi ṣùgọ́n ẹni ba fẹ́ débẹ̀, ẹsẹ̀ lásán ni yó fi gun àwọn àkàsọ̀ fún bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. Àtàrí àjànàkú ni wọ́n pè é fún wa, wọn ní kìí ṣe ẹrù ọmọdé o. Njẹ́ ẹ mọ̀n pé kòsí ẹni fẹ́ lọ. Bí ojú ṣe ro ẹnìkan ni ẹ̀rù ba ẹlòmíì. Àyàfi Alákọ̀wé yín àtàtà. Ṣé ẹ ti mọ̀n tẹ́lẹ̀ pé ọkùrin mẹ́ta ni mí? Ìwájú ni irúfẹ́ wa fi ń gbọta, àwa kìí ṣojo ní ìran wa rárá. Mo ní kí wọ́n ṣílẹ̀kùn fún mi kí n máa gùn’kè lọ. Èmi fẹ́ gùn ún dókè pátápátá.

DSCF0119

Nígbà tó yá mo kúkú dé òkè pátápátá bíótilẹ̀jẹ́pé ńṣe ni mò ń mín hẹlẹhẹlẹ lọ. Yàrá tí mo já sí jọ èyí tí mo tí ń bọ̀, àmọ́ ó kéré jù ú lọ. Èmi nìkan ni mo dá wà níbẹ̀. Ibi tí ilé náà ga dé, nígbàtí mo bojú wo ìta níbi fèrèsé, mo wá ń wo àwọn ìkúùkù òjò láti òkè wọ́n. N kò le rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń rìn nílẹ̀ mọ́n nítori mo ti jìnnà sókè jù. Ó dàbí ẹni pé mo wà nínú ọkọ̀ òfurufú ni. Atẹ́gùn ń gbé àwọn ìkúùkù funfun kọjá bí èéfín, mo sì rí òjiji ilé gogoro náà tó fà lé àwọn ìkúùkù ojo náà. Kódà, nkan ìyanu gidi ni. Àmọ́ nígbàtí mo fẹ́ máa padà lọ sílẹ̀, ni nkan tó jọmí lójú jùlọ ṣẹlẹ̀. Òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀. Ṣùgbọ́n èmi ń wò ó láti òkè, ó ń rọ̀ nísàlẹ̀ lé àwọn tó wà nílẹ̀ lórí. Oòrùn ló ràn lókè ọ̀dọ̀ tèmi. Nkan àràmàndà méèrírí gan-an ni. Kò ṣeé ṣàpèjúwèé dáadáa láìfojúrí fúnra ẹni.

DSCF0099

Wọ́n ní àjò kìí dùn ká gbàgbé ilé. Nígbà tó yá mo sọ padà sílẹ̀ mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ. Ọ̀nà igbó tí mo gbà tẹ́lẹ̀ kọ́ ni mo gbà padà o. Igbó olókìkí kan ni mo tọ̀ já. Àmọ́ gbogbo oun tí mo rí nínú igbó náà kàn ń múnmi yanu ni. Kí ló fa ìyanu? Ẹ̀yin ẹ padà wá ka apá kẹta ìtàn yìí láìpẹ́. N ó ṣàròyé ìdí abájọ, àti ìdí tí wọ́n fi ń pe igbó náà ní Igbó Funfun.

Àgádágodo aláwọ̀ ìyeyè

agadagodo_alawo_iyeye

Njẹ́ ibi orí dáni sí làá gbé. Ibi orí ranni lọ làá lọ. Bẹ́ẹ̀ iṣẹ́ ori ránni làá ṣe. Èyí ló fa máalọ-máabọ̀ ojoojúmọ́ gbogbo ẹ̀dá. Iṣé òòjọ́ wọn ni wọ́n ń ṣe. Ọ̀nà àti là yìí náà ni wọ́n ń lépa.

Máalọ-máabọ̀ ojoojúmọ́ yìí a máa sú ọ̀pọ̀lọpọ̀ dé’bi pé wọn kìí kíyèsí nkan lọ titi lọ́nà ibi tí wọ́n ń lọ. Kí wọ́n ṣáà tètè dé ibiṣẹ́, kí wọ́n tètè parí iṣẹ́, kí wọ́n sì tètè padà dé’lé ló jẹ wọ́n lógún.

Bí i tẹ̀mi Alákọ̀wé kọ́. Ní tèmi o, mo máa ń ṣí ojú mi kalẹ̀ dáadáa ní gbogbo ìgbà ni. Mo sì máa ń ṣe àkíyèsí gbogbo oun tí ń lọ ní àyíká mi. Èmi a máa rí àwọn nkan ìyanu káàkiri gbogbo ilẹ̀ tí mò ń tẹ̀, èmi a sì máa gbé orúkọ́ Ọlọ́run ga. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, n a máa rí ẹwà nínú àwọn nkan kékèké tí àwọn míràn ò kà kún nkankan. Ṣé bó ti wu Elédùà ló ń ṣ’ọlá ẹ̀? Ọba mi a ṣèkan bí àpáta gbànyàyà, Ọba kannáà yìí a ṣe òmíràn bí ọ̀kúta wẹwẹ tí ń bẹ nínú erùpẹ̀.

Èdùmàrè yìí tún ṣe iṣẹ́ ẹ̀ l’áṣepé, ó fi làákáyè jíìnkí ọmọ ẹ̀dá. Ó ní ká máa fi ọgbọ́n orí wa dárà ní ọlọ́kanòjọ̀kan. Irúfẹ́ àrà náà ni mo mà máa ń rí lọ́nà ibiṣẹ́ o. Àgádágodo aláwọ̀ ìyeyè ni nkan náà. Bíótilẹ̀jẹ́pé gbogbo èèyan tí wọ́n ń kọjá níbẹ̀ ò tilẹ̀ kíyè sí i, tàbí kí wọ́n rí i ṣùgbọ́n kí wọ́n má kà á kún nkankan. Àmọ́ èmi Alákọ̀wé, nkan arẹwà gbáà ni mo kà á kún. Tó fi jẹ́ pé mo mọ̀ńmọ̀ ya àwòrán rẹ̀ fún ayé rí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí ìmọ́lẹ̀ oòrùn tó lágbára jù, kí iyì àwọ̀ rẹ̀ lè hàn dáadáa. Ọ̀rọ̀ yìí á ti yé àwọn afẹ̀rọyàwòrán ẹgbẹ́ mi.

Ẹ̀yin náà ẹ wò ó. Njẹ́ ọ̀dà tí wọ́n kun àgádágodo yìí rẹwà àbí kò rẹwà? Ẹ jẹ́ kí n gbọ́ èsì yín o.

Ojúmọ́ gígùnjùlọ

oorun

Àwọn àgbà Yorùbá àtijọ́ a máà sọ̀rọ̀ kan. Wọ́ ní “oòrùn ló ni ọ̀sán, òṣùpá lo ni òru”. Òótọ́ ni. Àmọ́ ìyẹn lọ́dọ̀ tíwa lọ́hùún ni o.

Ẹ jẹ́ mọ̀n pé àwọn ibìkan ń bẹ tí oòrùn kò ní wọ̀ rárá lónìí? Bẹ́ẹ̀ni. Ajẹ́pé lọ́dọ̀ tiwọn níbẹ̀, àti ọ̀sán gan-gan o, àti gànjọ́ òru, ìkáwọ́ oòrùn ló wà. Ìyẹn lórí eèpẹ̀ àgbálá ayé wa yìí náà o.

Ní ìlú ọba níhìín, fún wákàtí mẹ́rìndínlógún àti ìṣẹ́jú méjìdínlógójì ni oòrùn yíò ran ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kalẹ̀ yanyanyan léwa lórí kó tó wọ̀ ni nkan bí i aago mẹ́sàn-án kọjá ìṣẹ́jú mọ́kànlélógún.

Aago mẹ́fà àbọ̀ ìrọ̀lẹ́ ni mo ya àwòrán yìí lónìí, àmọ́ ẹ wo bí oòrùn ti mún. Kódà ní ìta gbangba ńṣe ni oòrùn kanni látàrí gbọ̀ngbọ̀n.

Ìdí abájọ ni pé òní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù keje ọdún ni ojúmọ́ gígùnjùlọ lọ́dún ní ìhà àríwá àgbáyé. Mo ti ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ yìí rí níbìkan.

Òní tún bọ́ sí ọjọ́ Àbámẹ́ta tí í ṣe ọjọ́ ìgádùn kẹlẹlẹ. Ní tèmi Alákọ̀wé, fàájì ni mo wà o jàre.

Ìrìnkèrindò Moravia

IMG_5920
Yoòbá ní àìrìnjìnnà ni kò jẹ́ ká rí abuké ọ̀kẹ́rẹ́. Ẹ wo ibi Alákọ̀wé rìn dé tó fi rí abuké erin. Ìrìnkèrindò gidi rèé o, ẹ máa bá mi kálọ.

Ilẹ̀ kan ń bẹ láàrin gbùgbùn Úróòpù tí ń jẹ́ Moravia. Ilẹ̀ ọ̀hún kìkì òkè ni, ó sì kún fún àwọn igbó aginjù ńlá-ńlá àti adágún odò fífẹ̀ ní ọlọ́kanòjọ̀kan.

Èmi Alákọ̀wé yín àtàtà, mo fi ẹsẹ̀ mi méjéèjì tí Elédùà fún mi rin àwọn òkè náà. Mo sọdá àwọn odò tí wọn kò jìn púpọ̀jù, mo sì rìn nínú àwọn igbó wọnnì pẹ̀lú. Ó wá ṣe bí ẹni pé èmi gan-an ni ògbójú ọdẹ nínú igbó Maravia. Ṣùgbọ́n ìyàtọ̀ ibẹ̀ ni pé bíótilẹ̀jẹ́pé mo rí àwọn ẹranko kọ̀ọ̀kan t’ọ́n ṣàjèjì sí mi, n kò fojú kan ẹbọra tàbí abàmì ẹdá kankan o 🙂 . Ọpẹ́ ni fún Olódùmarè.

Àmọ́ ṣá, oríṣìíríṣìí lojú rí níbẹ̀ o. Nígbàtí mo dé ẹ̀bá igbó kan, mo ṣàdédé rí nkan tó jọ agbárí ìkookò tí ẹnìkan gbé kọ́ igi. Ó dẹ́ru báni púpọ̀. Nígbà tó tún ya mo tún ń wo nkankan lókèrè tó fẹ jọ òjòlá ńlá. Ó kù díẹ̀ kí n padà lọ́nà kí n tó rí i pé okun lásán ni mo rí.

IMG_5882

Oríta mẹ́ta kan ń bẹ lọ́nà àbáwọ igbó ńlá náà. Gbogbo òkúta ilẹ̀ ibẹ̀ funfun gbòò bí iyọ̀. Àsìkò ìwọ́wé tó jẹ, àwọn ewé ti wọ́ dà sílẹ̀, wọ́n wá pọ́n kuku. Gbogbo rẹ̀ wá ń tàn winiwini nínú ìmọ́lẹ̀ oòrun. Ó wuyì púpọ̀, kódà nkan ẹwà gidi gan-an ni.

IMG_5897

IMG_5902

Lẹ́hìn wákàtí mélòókan mo tọ igbó ọ̀hún ja sí ilẹ̀ ọ̀dàn ńlá kan tó lọ gbansasa kọjá ibi tí ojú ẹni ríran dé. Òkè kékeré kan ń bẹ láàrin ilẹ̀ ọ̀dàn náà. Ní orí òkè náà ni mo ti rí nkan ìyàlẹ́nu. Ilé gogoro kan mà ni o.

Ilé ọ̀hún ga tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, n kò lè fojú rí òkè rẹ̀ láti ìsàlẹ̀. Ó tún wá ṣe ṣoṣoro lókè, ó dàbí ẹni pé ó fẹ́ gún ojú-ọ̀run lábẹ́rẹ́. Àwọn kan ti wí fún mi tẹ́lẹ̀ náà pé àràmàndà ni ilé ọ̀hún jẹ́. Àmọ́ tí wọ́n bá wípé “Ìròhìn ò tó àmójúbà” bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ yìí rí. Kíákíá ni mo bá tẹsẹ̀ mọ́n’rìn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í tọ ilé náà lọ.

DSCF0038

Nígbà tí mo súnmọ́ ọ̀n díẹ̀ sí i, mo ṣàkíyèsí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan èjèèjì tí àwọn náà ń tọ ilé gogoro náà lọ. Ní òjijì ni gbogbo wọn bá dúró, wọ́n gbójú sókè. Èmi náà bá wòkè pé kí wa ló dé?

Ẹ̀rù Ọlọ́run sì bà mí. Òjò ti ṣú dẹdẹ lójijì. Àwọn ìkúùkù-òjò sì ti bo bí ìdajì ilé náà lókè. Àrá sán kàáwòóóó! Òjò bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀. Gbogbo wa bá bẹ́ sí eré sísá. A súré tete tọ ilé ọ̀hún lọ pé bóyá a lè rí ibìkan gọ sí kí gbogbo aṣọ wa má baà tutù tán.

Ṣùgbọ́n oun tó dẹ́rù Ọlọ́run bani lọ́jọ́ náà ni pé bí òjò ṣe ń rọ̀ lemọ́-lemọ́ lé wa lórí, bẹ́ẹ̀ oòrùn ń ràn kalẹ̀ níhà ibòmíràn, tí a sì ń wò ó lọ́ọ̀ọ́kán. Òṣùmàrè wá fà kàlákìní lójú ọ̀run. Ah! Ẹ̀yin èèyàn mi nkan ńbẹ o!

DSCF0056

Nígbà tó yá a kúkú dé iwájú ilé gígá roro náà. Ẹ bi mí pé kíni ojú mi rí níbẹ̀ ẹ̀yin èèyàn mi? Gbogbo rẹ̀ ni n ó rò fún yín ní apá kèjì ìtàn yìí. Ẹ padà wá láìpẹ́. Ẹ yíò ka bambarì ìtàn.

Ẹ kú ojú lọ́nà o 🙂