Ènìyàn àti Ṣúgà

Sibi Suga Yoruba
Yoòbá ò purọ́ nígbà tó wípé “a kìí fi oyin sẹ́nu ká tutọ́”. Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ni, ó sì nítumọ̀ púpọ̀. Àmọ́ bó ti nítumọ̀ ìjìnlẹ̀ náà ló ni ti eréfèé.

Àdídùn tí ń bẹ nínú oyin dára púpọ̀, ó sì kún nkan tí ara ẹni ń fẹ́. Ẹlẹ́dàá ló ṣe ètò oyin ṣíṣe, tí Ó sì fi fún kòkòrò abìyẹ́ nì láti máa ṣe.

Ní inú oje òdòdó ni kòkòrò oyin ti ń yọ àdídùn ṣe oyin. Nígbà tí mo wà ní kékeré, èmi àti ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi àti àwọn ọ̀rẹ́ wa máa ń fẹ́nu fa oje òdòdó mun. A máa dùn lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣé áńgẹ́lì ọmọdé ni kò jẹ́ ka pàdé èyí tó máa pa wá lára. Nígbà míràn gan-an ńṣe la máa kúkú sọ odidi òdòdó sẹ́nu kàló, tí a ó rún un lẹ́nu wọ̀mù-wọ̀mù, tí a ó sì gbé e mìn gbùn-ún, tí nkankan ò sì ní ṣe wá.

Ododo Yoruba
Bó ti wà láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé nìyẹn. Àwọn nkan tí Ẹlẹ́dàá ṣe, àwá ọmọ ènìyan pẹ̀lú, Ó ti fi ìbáṣepọ̀ sáàrin wa pé kí a jẹ́ aláànfàní arawa, kí a sì máa ṣe arawa lóore. Ìyẹn láàrin àwa ọmọ ènìyàn àti ẹranko gbogbo – ẹranko si ewéko, eweko sí ènìyàn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣùgbọ́n àwa ọmọ ènìyàn a kìí yé kọjá àyè wa. A ní ìrọwọ́-rọsẹ̀ tó ti wà láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àgbáyé yìí ò tẹ́ wa lọ́rùn o. A ní dandan àfi ká ṣe tí inú wa. A ní iṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ò dára tó, àfi ká tún un ṣe ní ìlànà tiwa. Àpẹrẹ ìwà yìí kan rèé;

Ẹ̀dá ọmọ ènìyàn kọ̀ ó ní oyin ò dùn tó o. Ó tún wípe rárá, ìrèké náà kù díẹ̀ káàtó. A ní àfí ká ṣe ìwádìí nkan tó fa adùn inú àwọn nkan wọ̀nyí, kí a lè ṣe wọ́n ní ìlànà tiwa.

Ọmọ ènìyàn bá fún omi inú ìrèké, ó gbé e raná ti omi náa fi gbẹ, tí ó fi ku kiní kan funfun báláhú. Kiní ọ̀hún jọ iyọ̀, àmọ́ dídùn rẹ̀ yàtọ̀ sí ti iyọ̀, ó jọ ti oyin àti ìrèké. Ẹ̀dá ọmọ ènìyàn ní “Kò tán bí!? A ti rí ìdí abájọ, ojú ti ẹ̀yin ọmọ kòkòrò!”.

Kokoro Oyin Cocacola Yoruba

Ọmọ ènìyàn wo kiní ọ̀hún títí ó ní “Ṣúgà la ó máa pè ọ́”

Ṣúgà amáyé dùn
Ìwọ ni gan-an ajẹmáleètu
Àdídù inú oyin abara funfun
Àní ìwọ gan-an lọ dùn jù
Ìwọ ni ìrèké gbóríyìn fún
Àwọ̀ àlà rẹ ń wọ̀ mí lójú

Kofi Yoruba Suga

Láti ìgbà yìí ni ọmọ èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ń tọ́ kiní funfun ọ̀hún sí gbogbo nkan jíjẹ àti mímu. Wọn a máa tọ́ ṣúgà sí omi. Wọn a máa tọ́ ọ sí ẹ̀kọ mímu. Kódà àwọn kan a máa lá a ní gbẹrẹfu.

Àwọn àgbàlagbà Yorùbá ti parí ọ̀rọ̀ tipẹ́-tipẹ́. Wọ́n ní “Àṣejù ni bábá àṣetẹ́”. Ọ̀rọ̀ àgbà rèé, kì báà pẹ́, a máa padà ṣẹ nígbẹ̀yìn ni. Nígbà tó yá, ifẹ́ àfẹ́jù tí ń bẹ láàrin ọmọ ènìyàn àti ṣúgà bá bímọ. Ìfẹ́ ọ̀hún ni àṣejù. Ọmọ náà ni àṣetẹ́.

Kí wá ló ṣẹlẹ̀? N ó fi tó o yín létí láìpẹ́. Ẹ padà wá gbọ́ àbọ̀ ọ̀rọ̀.

Ẹ ṣeun, mò ń bọ̀ ná.

Advertisements

Ojúmọ́ gígùnjùlọ

oorun

Àwọn àgbà Yorùbá àtijọ́ a máà sọ̀rọ̀ kan. Wọ́ ní “oòrùn ló ni ọ̀sán, òṣùpá lo ni òru”. Òótọ́ ni. Àmọ́ ìyẹn lọ́dọ̀ tíwa lọ́hùún ni o.

Ẹ jẹ́ mọ̀n pé àwọn ibìkan ń bẹ tí oòrùn kò ní wọ̀ rárá lónìí? Bẹ́ẹ̀ni. Ajẹ́pé lọ́dọ̀ tiwọn níbẹ̀, àti ọ̀sán gan-gan o, àti gànjọ́ òru, ìkáwọ́ oòrùn ló wà. Ìyẹn lórí eèpẹ̀ àgbálá ayé wa yìí náà o.

Ní ìlú ọba níhìín, fún wákàtí mẹ́rìndínlógún àti ìṣẹ́jú méjìdínlógójì ni oòrùn yíò ran ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kalẹ̀ yanyanyan léwa lórí kó tó wọ̀ ni nkan bí i aago mẹ́sàn-án kọjá ìṣẹ́jú mọ́kànlélógún.

Aago mẹ́fà àbọ̀ ìrọ̀lẹ́ ni mo ya àwòrán yìí lónìí, àmọ́ ẹ wo bí oòrùn ti mún. Kódà ní ìta gbangba ńṣe ni oòrùn kanni látàrí gbọ̀ngbọ̀n.

Ìdí abájọ ni pé òní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù keje ọdún ni ojúmọ́ gígùnjùlọ lọ́dún ní ìhà àríwá àgbáyé. Mo ti ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ yìí rí níbìkan.

Òní tún bọ́ sí ọjọ́ Àbámẹ́ta tí í ṣe ọjọ́ ìgádùn kẹlẹlẹ. Ní tèmi Alákọ̀wé, fàájì ni mo wà o jàre.

Ìmísí ayọ̀

Yoòbá ní “Kùtù-kùtù kìí jóni lẹ́sẹ̀ bí ọ̀sán”. Torí ìdí èyí, èmi a máa tètè jí ṣe oun tí mo ní ṣe lóòjọ́. Pàápàá nígbà ooru tí oòrùn máa ń tètè là ní ìlú yìí. Ojúmọ́ a ti sáré mọ́n ní nkan bí ago mẹ́fà òwúrọ̀.

Ṣùgbọ́n a ti kọjá ọjọ́dọ́gba tó síwájú ìgbà-ìwọ́wé (ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀ rèé). Ajẹ́pé àwọn ewé ti bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́ lórí àwọn igi.

Àpẹrẹ pé àwọn igi wọ̀nyí àti àwọn ewéko gbogbo ti ń gbáradì fún ọ̀gìnìntìn tó ń bọ̀ lọ́nà.

Ìgbà yìí a máa rẹwà púpọ̀. Àwọn ewéko a máa pa àwọ̀ dà, ewé wọn a máa pọ́n kuku, wọ́n a rí kàlákìnní.

Ṣùgbọ́n bótiwù kí òde rẹwà tó, àsìkò yí ni àmì ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn máa ń ṣábàá bẹ̀rẹ̀ sí í farahàn lára àwọn ènìà. Àwọn onímọ̀jìnlẹ̀ ni wọ́n mọn ìdí abájọ, àmọ́ àyípadà sí ètò ìlà àti ìwọ̀ oòrùn kópa nínú ìmúrẹ̀wẹ̀sìbáni yìí.

Síbẹ̀-síbẹ̀, àwọn nkankan a máa mú inú ẹni dùn. Fún àpẹrẹ, mo rí àwọn òdòdó kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ta, bótilẹ̀jẹ́pé ìgbà ìwọ́wé ni a wà yí. Mo tún rí àwọn ewé kọ̀ọ̀kan tí àwọ̀ wọ́n tanná niniini, bótilẹ̀ṣepé àwọn ewé ìyókù ti ń panná.

Eyí a máa fúnni ní ìmísí ayọ̀, a sì máa lé ìrẹ̀wẹ̀sì sí kọ̀ọ̀rọ̀. Mo kí gbogbo ẹni tó fi ìhà aríwá àgbáyé ṣe ibùgbé kú ìpalẹ̀mọ́ ọ̀gìnìntìn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ dé o.

Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la rìn wá

Onírúirú, oríṣìíríṣìí àti ọlọ́kanòjọ̀kan. Bẹ́ẹ̀ ni Ẹlẹ́dàá ṣe ṣ'ẹ̀dá ọmọ ènìyàn sí ilé-ayé. Ó wé Lágbájá ní àwọ̀ dúdú riri, Ó dá Tẹ̀mẹ̀dù ní aláwọ̀ ẹfun. Bí Ó ti dá kúkúrú ló dá gíga ẹlẹ́sẹ̀ gbọọrọ. Irun orí ẹnìkan a gùn a fẹ́lẹ́, ti ẹlòmíràn a sì hunjọ bíi kàìnkàìn. Irun lámọín pupa yòò bí iná tí ń jó, irun làkásègbè àfi bí adé òwú dúdú. Aṣẹ̀dá ọmọ ènìyàn dá abapá tínrín abẹsẹ̀ tínrín bíi ẹyẹ lékeléke. Kò sì ṣàìdá alápá ńlá ẹlẹ́sẹ̀ gòdògbà bí àjànàkú.

Àbí ẹ kò rí imú àwọn kan pẹlẹbẹ bí ìgbákọ? Ó ṣeé kọ àmàlà ní'kòkò. Bẹ́ẹ̀ imú àwọn míì sọsọrọ bí akọ́rọ́ tó ṣeé ká ọsàn lórí igi. Ètè ńkọ́? A rí èyí tó fẹ́lẹ́ bí abẹ̀bẹ̀. Òmíì sì rèé kíki pọ́npọ́n bíi pọ̀nmọ́. Ẹ wo onírúirú agbárí ọmọ ẹ̀dá. Òmíì róbó-róbó bí àgbọn, bẹ́ẹ̀ Ẹlẹ́dàá fi ìpàkọ́ lànkọ̀ ta ẹlòmíì lọ́rẹ. Orí a wá ṣe rìbìtì bí Olúmọ, orí enítọ̀hún a wá máà júbà orígun mẹ́rẹ̀rin ayé bí ó ti ń rìn lọ.

Gíga sókè ọmọ ènìyàn, àṣé kìí ṣe nípasẹ̀ ẹsẹ̀ gígùn nìkan. Olódùmarè tún ṣ'ẹ̀dá ẹlẹ́sẹ̀ kúkúrú, Ó wá fi ọrùn gígùn dá a lọ́lá. Olúwarẹ̀ a wá jọ ògòngò baba ẹyẹ. Ẹ̀dá míràn dẹ̀ rèé kò ní ọrùn kankan rárá. A jẹ́ pé enítọ̀hún di ẹbí ìjàpá tìrókò ọkọ yáníbo.

Ọ̀kan ṣoṣo ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Olódùmarè ṣe ẹ̀dá olúkálukú. Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la rìn wá, gẹ́gẹ́ bí òwe Yorùbá kan, ilé-ayé la ti pàdé.

 

Ọ̀gìnìntìn Olórí Kunkun

Àsìkò ìrúwé la wà yí. Àsìkò yí ni ewé titun, ewé tútù ń so lórí igi. Ìgbà yí ni àwọn òdòdó aláràbarà ń so lórí àwọn ewéko ab'òdòdó gbogbo. Òtútù yẹ kó ti máa dínkù. Gbogbo ibi tí yìnyín ti ń rọ̀, ó yẹ kí ó ti máa dáwọ́ dúro. Kí ooru oòrùn ti máa yòòrò gbogbo omi-dídì káàkiri àgbàyé. Ní ìhà àríwá àgbáyé ni o.

Àmọ́ ọ̀gìnìntìn f'àáké kọ́rí, ó l'óun ò re'bìkan. Òtútù kọ̀ ó l'óun ò ní dá gbére lótẹ̀ yìí. Ó l'óun ò ní dákẹ́ ariwo ẹ̀fúùfùlẹ̀lẹ̀ tútù nini. Kàkà kó ká'gbá ń'lẹ̀ kó máa re'lé, ńṣẹ ló tún rọ funfun sílẹ̀ bí èlùbọ́. Ó fẹ́ tútù nini tí gbogbo aráyé ń gbọ̀n tí wọ́n ń wa'yín keke. Aráyé ti ìhà àríwá là ń wí sẹ́ẹ̀.

Ọ̀gìnìntìn dákun kẹ́rù rẹ máa lọ. Èyí o ṣe yìí náà tó o jàre. Àṣejù baba àṣetẹ́. Jẹ́ kí àwọn òdòdó ráàyè ta. Jẹ́ kí àwọn nkan-ọ̀gbìn ráàyè yọrí jáde l'éèpẹ̀. Jẹ́ kí Alákọ̀wé ráàyè gbé ẹ̀wù kànkà yìí pamọ́ o jàre. Ara ń fẹ́ ìsinmi.