Abúlé Stratford

Apá keta ti bà bí àdàbà o. Ẹ bámi dé abúlé kan ní Lọndọn tí wọ́n ń pè ní Stratford. Ibẹ̀ ni ìdíje Olympics ti ṣẹlẹ̀ ní ìdun-ùnta, ìyẹn l’ọ́dún mẹ́ta sẹ́yìn.

Ire o!

Advertisements

Yakubu Adesokan ṣe oríire

Ìwúrí àti àyọ̀ nlá ni fún gbogbo ọmọ Yorùbá àti gbogbo Nàìjíríà lápapọ̀ lónìí! Ọmọ ìyá wa Yakubu Adesokan ló mà fúnwa láyọ̀ o. Adesokan jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn eléré ìdárayá wa tí Nàìjíríà rán lọ́ ibi ìdíje Paralymics tó nlọ lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí ní ìlú London. Arọ ni alákùnrin yìí jẹ́, iye ọjọ́ orí i rẹ̀ sì nṣe mẹ́tàlélọ́gbọ̀n. Ẹré tirẹ̀ jẹ́ ìdíje ìgbẹ́rùwíwo sókè.

Lásán kọ́ ni pé alákùnrin yìí gbé ipò kíní, ìyẹn ni pé ó gba wúrà, ìwọ̀n ẹrù tó rí gbé sókè, kò tíì sí ẹni ẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ kankan tó gbé ìwọ̀n wíwo báyìí rí! Ìyẹn ni pé láti ìgbà tí ìdíje yìí ti bẹ̀rẹ̀, Yakubu ni ipò kíní pátápátá. Àb'ẹ́ẹ̀ rí nkan?

Ọjọ́ ìkíní rèé o, a ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. 'Ó tún kù!' ni ìbọn nró!

Àjọ̀dún Notting Hill

Ijó rẹpẹtẹ. Ìlù rẹpẹtẹ. Orin rẹpẹtẹ. Àríyá rẹpẹtẹ ló ṣẹlẹ̀ ní àdúgbò ìwọ̀-oòrùn London. Gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ lọ́dọọdún, àjọ̀dún Notting Hill ló gbọ̀de lọ́jọ́ Àìkú àti ọjọ́ Ajé tó kọjá.

Ní ọdún 1965 ní àjọ̀dún yìí kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀. Àwọn tí wọ́n wá láti àwọn erékùṣù Caribbean (tí wọ́n jẹ́ ìran adúláwọ̀ tí àwọn òyìnbó kó lọ sóko ẹrú láíyé àtijọ́) ní wọ́n dáa sílẹ̀. Pàápàá jùlọ àwọn ará ìlú Trinidad. Lóde òní wàyí, ó ti di ayẹyẹ gbogbo gbòò, gbogbo ẹ̀yà, gbogbo ìran ni.

Iyé ènìà tó pé jọ fún ayẹyẹ náà lé ní 1,000,000! Kò tún sí ibòmíràn ní gbogbo àgbáyé tí èro pọ̀ báyìí fún ayẹyẹ àjọ̀dún ti gbangba ojú títì, àfi ní ìlú Rio de Janeiro ni orílẹ̀ Brasil. Iṣẹ́ nlá ni fún àwọn ọlọ́pàá nítorí ojúṣe wọn ni láti pèsè àbò àti ìdarí èrò nlá yìí. Nítorí èyí, àwọn ọlọ́pàá a máà gbáradì fún oṣù mélòó kan kí ayẹyẹ náà tó wáyé. Pàápàá ní ọdúnnìí tó tún bọ́ sí àrin ìdíje nlá méjì tí ìlú London gbà lálejò.

Bótilẹ̀jẹ́pé ọ̀nà kannáà ni wọ́n ngbà lọ́dọọdún, àwọn olùdarí ètò ayẹyẹ a máa gbìmọ̀pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá láti ríi dájúdájú pé kò sí ewu kankan lọ́nà tí gbogbo ètò náà á tọ̀ kọjá.

Àti pé nítorí púpọ̀ nínú awọ̀n ọ̀nà wọ̀nyí gba iwajú ilé àwọn ènìà kọká. Àwọn ọlọ́pàá a sì máa gbe igi dínà tàbí kí wọ́n o kan ọgbà dí àwọn ọ̀nà kékèké kan tó bá gba àrin'lé ẹlòmíràn kọjá. Gbogbo ẹ̀ náà láti dáàbò bo nkan ìní àti dúkìá àwọn ará àdúgbò ibẹ̀ ni.

Àwọn ọkọ̀ agbérò nlá nlá ni wọ́n máa nkó àwọn ẹ̀rọ gboùngboùn sí tí wọ́n a máa fi gbóùn àti orín sáfẹ́fẹ́ fún ìgbádùn gbogbo èrò. Àwọn ọmọ oníjó a sì máa jó tẹ̀lé àwọn ọkọ̀ nla wọ̀nyí títí wọ́n á fi tọ ọ̀nà já. Àwọn ọmọ oníjó wọ̀nyí, púpọ̀ nínú wọn a máa wọ aṣọ bí eléégún aláràbarà. Nítorí àwọn ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan ní wọ́n njó tẹ̀lé ọkọ̀ tiwọn, wọn a máa mú u bí ìdíje ni. Ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan a fẹ́ dárà jú àwọn ìyókù lọ.

Wọ́n a tún máa to àwọn ẹ̀rọ gboùngboùn agbóùnsáfẹ́fẹ́ sí àwọn òpópónà kàn tí àwọn òṣèré á máa lú onírúirú àwo olórin fún ìgbádùn àwọn èro tí wọ́n péjọ sọ́dọ̀ ọ wọn. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ìsọ̀ olóúnjẹ́ onikanòjọ̀kan náà máa nwà káàkiri fún àwọn èrò láti ra óújẹ jẹ. Fún ọjọ́ méjì gbáko ni àríyá yìí lọ. Bótilẹ̀jẹ́pé àwọn màndààrú àti jàgùdà kọ̀ọ̀kan ò lè sàì wà níbẹ̀, àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ a máa mu igbó níbẹ̀, gbogbo ẹ̀ a máa sábàá lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀ ni.

Ìdíje àwọn àkàndá àti abarapa ẹ̀dá

 
Ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́hìn tí wọ́n parí Ìdíje London 2012, abala kejì tí wọ́n npè ní Paralimpics á bẹ̀rẹ̀. Paralimpics yìí jẹ́ Ìdíje àwọn àkàndá àti abarapa ẹ̀dá. Ìyẹn ni pé gbogbo àwọn eléré ìdárayá tí wọ́n máa kópa nínú ìdíje náà a jẹ́ àkàndá àti abarapa ẹ̀dá bákan. Òmíràn nínú wọn á ní ẹsè eyọ ìkan péré. Ẹlòmíràn lè jẹ́ afọ́jú, arọ, alápá'kan, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìdíjẹ yìí a máa ṣẹlẹ̀ ní ibìkannáà tí Olympics ti ṣẹlè. Ọ̀pọ̀ nínú eré-ìdárayá kannáà dè ni wọ́n nṣe pẹ̀lú. Bíótilẹ̀jẹ́pé ọ̀tọ̀ ọ̀tọ̀ ni oun tí nṣe kálukú, àwọn olùdarí ètò a máa gbìyànjú púpọ̀ láti ríi pé wọ́n to àwọn eléré yìí pọ̀ bí ó ṣe tọ́ àti bí o ṣe yẹ.

Ní 1948 ní wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìdíje yìí ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn ògbó-jagunjagun tí wọ́n fi ara pa lójú ogun gbogbo àgbáyé kejì ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ rẹ̀. Àmọ́ ní ìwòyí, ìdíje náà ti gbòòrò dáadáa. Orísìírísìí àfikún sì ti dé bá a. Fún àpẹrẹ, tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, kò sí ànfàní fún ẹní tí a gé lẹ́sẹ̀ láti sáré. Ṣùgbọ́n lóde òní a ti ṣẹ̀dá onírúirú nkan amáyérọrùn fún àwọn abirùn. Ẹni a gé lẹ́sẹ̀, wọ́n ti ṣẹ̀dá irú ẹsẹ̀ kan fún wọn pẹ̀lú irin. Ẹsẹ̀ yìí ṣé é sáré dáadáa. Kódà ení bá mọ̀ ọ́ lò dáadáa lè sáré kíakía bí eni tí kò gé lẹ́sẹ̀ rárá ni. Ọ̀gbẹ́ni Oscar Pistorius jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn eni àkàndá àti abarapa olókìkí tí wọ́n nlo ẹsẹ̀ oní'rin. Ọ̀gbẹ́ni yìí mọ ẹsẹ̀ yìí lò dé ibi pé ó kópa nínú Olympics gan-an alára!

Ìwúrí gidi ni tí ènìà bá nwo àwọn eléré ìdárayá wọ̀nyí bí wọ́n ti nṣeré wọn takuntakun. Nígbàmíì àwa ọmọ ènìà máa nfi àwọn àkàndá àti abarapa ẹ̀dá si ipò àbùkù àti ẹ̀kọ̀ ni. Sùgbọ́n irú ìdíje yìí a máa múni rántí pé ọmọ ènìà kannáà jọ ni gbogbo wa!

London 2012

Fún ọjọ́ mẹ́tàdínlógún gbáko, àwọn eléré idárayá ọlọ́kanòjọ̀kan péjọ sí ìlú London fún ìdíje gbogbo àgbáyé tí a mọ̀ sí Olympics. Àwọn elére ìdárayá 10,820 ni wọ́n wá láti orílẹ̀èdè 204 lórígun mẹ́rẹ̀rin aiyé.

Irúfẹ́ eré ìdárayá mẹ́rìdínlọ́gbọ̀n ló wà ní ìdíje náà. Wọ́n tún pín àwọn òmíran nínú àwọn eré wọ̀nyí sí ìlànà bí àwọn eléré bá ṣe wúwo sí. Fún àpẹrẹ – ìdíje ẹ̀ṣẹ́ jíjà – ẹni wúwo a bá wúwo jà, ẹní fẹ́lẹ́ a bá ẹni fẹ́lẹ́, fúyẹ́ náà a sì dojúkọ fúyẹ, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ. Gbogbo ẹ̀ wá lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta.

Ọdún mẹ́jọ ni ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi ṣe ìpalẹ̀mọ́ ìdíje nlá náà. Owó iyebíye sì ni wọ́n nán s’órí ẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí iyé owó tí ìjọba ná, àwọn kan gbógun tì wọ́n pé àṣìṣe gbáà ni gbígbé ìdíje náà wá sí London. Ṣùgbọ́n gbogbo ìpalẹ̀mọ́ ọdún mẹ́jọ náà mú ilọsíwájú nlá bá agbègbè ibi tí ètò náà ti wáíyé. Kódà, ìdàgbàsókè gidi ló jẹ́. Yàtọ̀ sí pápá eré ìdárayá nlá tí wọ́n kọ́ sí Stratford, àìmọyé ilé tuntun ni wọ́n kọ́ sí gbogbo agbègbè tó súnmọ́ Stratford. Bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n kọ́ Westfield tí í ṣe àkójọpọ̀ àwọn ilé ìtajà nlá-nlá lábẹ́ òrùlé kan-ṣoṣo! Westfield náà tóbi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, kò l’ẹ́gbẹ́ kankan ní gbogbo ilẹ̀ Yúroòpù rárá!

Nínú eré kọ̀ọ̀kan, àyè mẹ́ta ló wà gẹ́gẹ́ bí àwọn tó yege. Ipò kíní, ipò kejì àti ipò kẹta. Ìkárùn oní wúrà ni fún ipò kíni, fàdákà fún ipò kejì ati idẹ fún ipò kẹta. Àwọn ìyókù a sì padà sílù wọn l’áìgba nkakan. Nígbàtí gbogbo rẹ̀ bá parí tí olúkálùkù ti gba ìkárùn ẹ̀yẹ rẹ̀, wọ́n a wá sírò gbogbo rẹ̀ pọ̀ fún Orílẹ̀èdè kọ̀ọ̀kan. Orílẹ̀èdè tó bá gba wúrà jù a bọ́ sí ipò kíní, bíótilẹ̀jẹ́ pé orílẹ̀èdè míràn gba fàdákà jù ú lọ. Tí orílẹ̀èdè méjì bá jọ gba iye wúrà kannáà, wọ́n á ka fàdákà wọn, lẹ́hìn ìyẹn, wọ́n á ka iye idẹ wọn títí tí wọ́n á fi to gbogbo orílẹ̀èdè t’ọ́n rí nkan gbà sípò.

Ní London 2012, America ló yege ipò kíní. China ṣe ipò kejì, Great Britain tó gbà’lejò ṣe ipò kẹta! Ìdùnnú nlá ló jẹ́ fún gbogbo Great Britain pé àwọn elére ìdárayá wọn ṣe dáadáa jù bí wọ́n ṣe rò pé wọ́n a ṣe lọ. Wúrà mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ni wọ́n rí gbà. Àwọn elére ìdárayá wọ̀nyí wá di àmúyangàn, òkìkí wọ́n sì kàn káàkiri ìlú.

Nigeria jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn orílẹ̀èdè tí kò rí nkankan gbà. Njẹ́ ìtìjú nlá kọ́ lèyí jẹ́ fún adúrú orílẹ̀èdè yìí tí a sọ lórúkọ "òmìrán Afíríkà" !!