Ilẹ̀-Ìyanu Ọ̀gìnìntìn

Ìgbésí ayé Alákọ̀wé apá kejì ti bọ́ o. Ẹ bá mi dé Ilẹ̀-Ìyanu Ọ̀gìnìntìn tí ń bẹ nínú ọgbà ńlá Hyde Park.

Ẹ má gbàgbé láti tẹ̀lé mi lórí YouTube o, kí n lè mọ̀n dájú pé ẹ ń gbádùn mi. Ṣé ẹ̀yin gbọ́rọ̀-gbọ́rọ̀ ni ọ̀gá àwa sọ̀rọ̀-sọ̀rọ̀.

Ẹṣeun púpọ̀ o.

Advertisements

Ẹkú Ọdún Kérésìmesì

Ẹkú Ọdún Kérésìmesì.

Ìmọ́lẹ̀ l'ọkọ òkùnkùn

Ìjẹta, mọ́júmọ́ àná, ni ọjọ kọkàlélógún sí ìkejìlélógún oṣù kejìlá ọdún. Alẹ́ yìí ni alẹ́ gígùnjùlọ lọ́dún. Fún wákàtí mẹ́rìndílógún gbáko ni òkùnkùn ṣú biribiri, ìyẹn ní Ígíláàndì ní’hàhín. Ní’hà ibòmíì, ilẹ̀ ṣú fún wákàtí mọ́kànlélógún. Kódà, a rí ibi tí ilẹ̀ ò tilẹ̀ mọ́n rárá lọ́jọ́ náà. N kò fi parọ́ rárá.

Ọpẹ́lọpẹ́ iná tí kìí lọ, tí kìí dákú ní’lẹ̀ yìí. Gbogbo ojú títì a tanná niniini. Láàrin òru gan-an, gbogbo ilé ní ìgboro ìlú a tanná kalẹ̀ gbòò. Gbogbo ẹ̀ á wá mọ́nlẹ̀ dáadáa.

Pàápàá jùlọ, àsìkò tí a ti súnmọ́ àjọ̀dún kérésìmesì gbọ̀ngbọ̀n, oríṣìíríṣìí iná aláràbarà ni àwọn ará ilẹ̀ yìí fi ń ṣe ìgboro wọn lọ́ṣọ̀ọ́. Yirinyirin aláràbarà ọlọ́kanòjọ̀kan ni èèyàn a máa rí níbikíbi tí èèyàn bá lọ. Ó wuyì gbáà.

 

Ìmọ́lẹ̀ l’ọkọ òkùnkùn

Ìjẹta, mọ́júmọ́ àná, ni ọjọ kọkàlélógún sí ìkejìlélógún oṣù kejìlá ọdún. Alẹ́ yìí ni alẹ́ gígùnjùlọ lọ́dún. Fún wákàtí mẹ́rìndílógún gbáko ni òkùnkùn ṣú biribiri, ìyẹn ní Ígíláàndì ní'hàhín. Ní'hà ibòmíì, ilẹ̀ ṣú fún wákàtí mọ́kànlélógún. Kódà, a rí ibi tí ilẹ̀ ò tilẹ̀ mọ́n rárá lọ́jọ́ náà. N kò fi parọ́ rárá.

Ọpẹ́lọpẹ́ iná tí kìí lọ, tí kìí dákú ní'lẹ̀ yìí. Gbogbo ojú títì a tanná niniini. Láàrin òru gan-an, gbogbo ilé ní ìgboro ìlú a tanná kalẹ̀ gbòò. Gbogbo ẹ̀ á wá mọ́nlẹ̀ dáadáa.

Pàápàá jùlọ, àsìkò tí a ti súnmọ́ àjọ̀dún kérésìmesì gbọ̀ngbọ̀n, oríṣìíríṣìí iná aláràbarà ni àwọn ará ilẹ̀ yìí fi ń ṣe ìgboro wọn lọ́ṣọ̀ọ́. Yirinyirin aláràbarà ọlọ́kanòjọ̀kan ni èèyàn a máa rí níbikíbi tí èèyàn bá lọ. Ó wuyì gbáà.

 

Ajíṣe bí Ọ̀yọ́ làá rí

Lónìí òpin ọdún 2012, tí a bá bojú wẹ̀hìn, a ó rí i pé ọ̀pọ̀ òjò ló ti rọ̀ lọ́dúnnìí, tí ilẹ̀ sì fi mu. Oríṣìíríṣìí nkan olókìkí ló ti ṣẹlẹ̀ ní Naijiria àti ni gbogbo àgbáyé. Àwọn nkan rere àti àwọn nkan búburú pẹ̀lú. Ọdún 2012 ni ìdíje Olympics wáyé ní ìlú Lọndon. Ọdún yìí náà ni wọ́n tún Obama yàn gẹ́gẹ́ bí ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹrika. Àwọn ìròhìn ayọ̀ oníkanòjọ̀kan náà la gbọ́ káàkiri àgbáyé.

Àmọ́ o, bí ó ti ntutù níbìkan ní í gbóná ní ibòmíràn. Àìmọye jàmbá la gbọ́ pé ó ṣelẹ̀ káàkiri àgbáyé lọ́dúnnìí. Ẹnìkan ló fi ikú ìbọn rán àwọn ọmọdé kékeré lọ sọ́run òjijì ní Amẹrika ni ìjọ́sí. Bẹ́ẹ̀náàni ààrẹ orílẹ̀ Síríà kò dáwọ́ pípa àwọm ọmọ ìlú rẹ̀ dúró. Àwọn ìjì nlá-nlá tún jà káàkiri àgbáyé, tí wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá lọ́. Ní Naija, ọkọ̀ òfurufú kò yéé jábọ́. Àwọn òlóṣèlú oníwàìbàjẹ́ ò yéé hùwà wọn. Àmọ́n èyí tó kanni lóminú jù ni ti àwọn alákatakítí Boko Haram, tí wọ́n ndúnbú ọmọ ènìyan bí eran lásán.

Ṣùgbọ́n ìrírí ayọ̀ ni tiwa ní ilẹ̀ Yorùbá ni ti ẹlẹ́sìn dé o. Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ẹlẹ́sìn Kiristẹ́nì àti Mùsùlùmí kìí bárawọn ṣe dáadáa ní gbogbo ibòmíràn, irẹ́pọ̀ gidi ló wà láàrin àwọn ẹlẹ́sìn méjéèjì ní ilẹ̀ Káàárọ̀-oòjíire. Kò ṣọ̀wọ́n ká rí ṣóòṣì àti mọ́ṣáláṣí tí wọ́n kọ́ si ẹ̀gbẹ́ arawọn. Ka rí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ to já èrò sílẹ̀, kí lágbájá kọrí sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ ké alelúyà, ki tẹ̀mẹ̀dù náà sì gba mọ́ṣáláṣí lọ rèé ké láìláà. Bó ti rí gẹ́lẹ́ ní ilẹ̀ Yoòbá nìyẹn láìsí ìjà, láìsí rògbòdìyàn.

Ní ọdún 2013 tó wọlé dé yìí, aríkọ́ṣe àti àwòkọ́ṣe ni ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ fún gbogbo àgbáyé nípa ìrẹ́pọ̀ èsìn. “Ajíṣe bí Ọ̀yọ́ làá rí o….” Kí gbogbo wa káàkiri àgbáyé jáwọ́ nínú ìwa ẹlẹ́sìnmẹ̀sìn tó nkó jambá nlá ba ilé-ayé yìí. Ọlọ́run níkan ló mọ ẹni tí ó là o.

Ọjọ́ mẹ́wàá péré lókù

Àwọn ẹ̀yà ayé àtijọ́ kan tí wọ́n pe orúkọ wọn ní Maya sọ wipé ayé á parẹ́ ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kejìlá ọdún 2012. Ọjọ́ mẹ́wàá òní ni ọjọ́ náà pé o! Njẹ́ lóòótọ́ ni ayé máa parẹ́ bí?

Bótilẹ̀jẹ́pé àwọn ẹ̀yà Maya ti parẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé ní nkan bíi ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́hìn, òkìkí wọn ti kàn gidi gidi lọ́dúnnìí nítorí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ wọn yìí. Lóòtọ́ ná, bí eré bí àwàdà ni púpọ̀ nínú wa fi nṣe, àmọ́ àwọn kan ní ìgbàgbọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, wọ́n ti lọ́ ba sórí àwọn àpátá nlá-nlá. Irú èyí nṣẹlẹ̀ lọ́wọ́-lọ́wọ́ ní ìlú Faransé, Séríbíà, ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ní tèmi o, mo mọ̀n dájú pé kòs'ẹ́ni mọ̀la. Ṣùgbọ́n ó múmi ronú pé tí ayé bá máa parẹ́ kí Kérésì tó dé, njẹ́ èmi ti ṣetán láti pàdé Ẹlẹ́dàá báyìí? Àti pé kíló kù nlẹ̀ tí ng kò tíì ṣe?

Ọjà Kérésìmesì Jamani

Gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn ní Lọndon lọ́dọọdún tí Kérésìmesì bá ti nsúmọ́, Ọgbà Hyde Park ti paradà di Winter Wanderland. Ìlú Jamani ni wọ́n ti kọ́ àṣà yìí, ó dẹ̀ hàn gedegbe bẹ́ẹ̀ nítorí pé ọjà-kérésìmesì-Jamani ni wọ́n npèé. Nkan oníkanòjọ̀kan àti onírúirú ló wà níbẹ̀ fún ìgbádùn tọmọdé tàgbà. Oríṣìíríṣìí onjẹ ni ènìyàn lè rí ràjẹ pẹ̀lú, pàápàá láti ìlú Jamani. Ọtí kan wà níbẹ̀ tí wọ́n npè ní mulled wine tó gbọ́nà fẹli-fẹli. Ọtí náà wọ́pọ̀ ní mímu nígbà òtútù ọ̀gìnìntìn ní orílẹ̀ Jamini àti káàkiri Úróòpù.

Nkan bí oṣù kan àbọ̀ ni ọgbà yìí ṣí fún. Ìyẹn ni pé ènìyàn ní ànfàní àti lọ síbẹ̀ títí di ọdún tuntun. Àmọ́ ìkìlọ̀ nlá rèé o: ẹni bá fẹ́ lọ kó yàá mú owo lọ́wọ́ o, nítorí nkan rọra gbówó lórí díẹ̀ níbẹ̀. Kí enítọ̀hún sì dì-káká dì-kuku bíi Baba Sùwé kó má baà ganpa nínú òtútù!