Èkó

Ẹ ǹlẹ́ o ẹ̀yin ẹ̀dá Ọlọ́run wọ̀nyí. Fún apá kẹfà Ìgbésí-ayé Alákọ̀wé, ẹ fìkàlẹ̀ lé e pẹ̀lú mi nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yìí. Ẹ jẹ́ ká dé Ìpínlẹ̀ Èkó, ká wòran díẹ̀.

Ní gbogbo ìgbà, èmi a kúkú máa kan sáárá sí gómìnà Èkó àná – Alàgbà Raji Faṣọla. Iṣẹ́ ńlá ló ṣe. Àyípadà tó dé bá ìpínlẹ̀ yìí ò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn rárá. Ó sì sọ Èkó di ibi àmúyangan – ibi iyì, ibi ẹ̀yẹ.

Nígbà kan rí, èmi ò kí ń fẹ́ rìn tí ilẹ̀ bá ti ṣú. Àmọ́ lóde òní, ẹ̀rù ò ṣábà á ba’ni mọ́n. Ọpẹ́ ni f’Ólúwa fún àwọn àyípadà rere wọ̀nyí. A ò ní ri àpadà sí burúkú láí-láí o. Kí gómìnà òní yáa múra síṣẹ́ gidi-gaan ni.

Ẹ ò jẹ́ ká dánu dúró ń’bẹ̀un bí? Wọ́n ní “ọ̀rọ̀ púpọ̀, irọ́ ní í mú wá”. Yoòbá káàbọ̀. A jẹ́ pé mo kí gbogbo yín kú ọdún titun o. Ọdúnnìí, á sàn wá s’ówó, sàn wá s’ọ́mọ, sàn wá sí àláfíà – tí í ṣe baálẹ̀ ọrọ̀.

Àṣẹ.

Advertisements

Ebola

Kokoro_Ebola
Mo kí gbogbo yín o. Ẹ kú ọjọ́ mẹ́ta. Ẹ sì kú àìfaraálẹ̀ náà. Olúwa yó máa fúnwa ní alékún okun àti agbára o.

Toò, ọ̀rọ̀ ló kó mokó morò wá. Èé ti rí? Ọ̀rọ̀ Ebola yìí mà ni o. Kòkòrò búburú tí í fa àjàkálẹ̀ ààrùn. Kòkòrò tí kò gbóògùn.

Bóo la ti wá fẹ́ ṣe é o? Ibo là á gbe gbà? Àwọn oní Bókobòko níwá, Èbólà lẹ́hìn. Àfi kí Elédùà kówa yọ.

Àmọ́ ṣá, Yoòbá ti wípé ojú l’alákàn fi ń ṣọ́rí. Kí oníkálukú yáa tẹra mọ́n ètò ìmọ́ntótó rẹ̀. Kí ó sì máa ṣe àkíyèsí gbogbo nkan tí ń lọ ní’tòsí.

Orísìírísìí là ń gbọ́ nípa kí la lè ṣe láti dáàbò bo’ra ẹni. Àwọn kan ní omi gbígbóná àti iyọ̀ ni ká fi wẹ̀. Kíá ni àti mùsùlùmí àti kìrìstẹ́nì ń da omígbóná ságbárí. A tún gbọ́ pé orógbó tàbí obì ni àjẹsára tọ́n lè báni yẹra fún ààrùn Ebola. Wéré ni tọ́mọ́ndé tàgbà ń rún orógbó lẹ́nu bí i gúgúrú, tí wọ́n sì ń jẹ obì bí ẹní jẹ̀pà. Àt’orógbó àt’obì o, wọn ò ṣé rà lọ́jà mọ́n, ńṣe ni wọ́n gbówó lérí tete.

Bẹ́ẹ̀ rèé ènìyàn ò báà bẹ́ sínú àmù ọmígbóná oníyọ̀, kó jẹ́ orógbó agbọ̀n kan, kó sì jẹ obì tó kún apẹ̀rẹ̀. Tí olúwarẹ̀ bá ko Ebola, tí kò bá ṣe àfira wá nkan ṣe, ṣàngbà fọ́ nìyẹn – ó di gbére.

Èmi wí tèmi, àmọ́ ẹnu ọlọ́rọ̀ lọ̀rọ̀ ti ń dùn. Ẹ fetí sí ètò Yorùbá Gbòde níbi tí olóòtú Ṣọla Yusuf ti gba amòye onímọ̀ nípa Ebola, tí wọ́n sì làwá lọ́yẹ̀ dáadáa.

Ẹ máa ṣe pẹ̀lẹ́-pẹ̀lẹ́ o. Ìpàdé wa bí oyin o. Ire o.

Ẹgbẹ̀rún mẹ́ta

United Kingdom kìkì ọmọ Nàìjá, pàápàá ọmọ Yorùbá. Ojoojúmọ́ ni ọkọ̀ ofurufú ń kó wọn wọ̀lú lọ́gọọgọ́rùn-ún wọn. Kíni wọ́n ń wá? Àròyé pọ̀ níbẹ̀. Ẹ jẹ́ ká mú u lọ́kọ̀ọ̀kan ní ṣókí-ṣọ́kí.

Gbogbo wa la mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ọmọ Naija ni wọ́n bí sí UK, ọ̀pọ̀ náà ló sì ti di ọmọ ìlú náà nípasẹ̀ ìwé-ìgbélùú gbígbà. Àwọn wọ̀nyí ní ẹbi àti ọ̀rẹ́ tí wọ́n a máa wá bẹ̀ wọ́n wò. Ìyẹn ení.

Ọlọ́run Ọba nìkan ló mọ iye ọmọ Naija to ń lọ àwọn ilé-ìwé gíga ní Orílẹ̀èdè UK lọ́dọọdún. Àwọn wọ̀nyí náà a máa gba tẹbí-tará ní àlejò láti ìgbàdégbà. Èyun èjì.

Ẹlòmíràn kàn ṣeré wá láì ní ẹbí kankan tàbí ará nílùú ọba nì. Ód'ẹ̀ta.

Àmọ́ àwọn tí ọ̀rọ̀ mí kàn lónìí ni àwọn oníṣòwò wa. Àwọn ti wọ́n ń torí káràkátà tẹsẹ̀ bọ ìrìnàjò àràmàndà wá sí UK. Àwọn tí wọ́n ń tọwọ́ b'àpò mú owó ọkọ̀ jáde san fún ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú. Ṣé mo ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìyànjẹ owó ọkọ̀ ofurufú nígbàkan? Owó kékeré kọ́ ni àwọn èèyàn wa ń ná dà sí ìlú yìí o. Ẹ̀yin ẹ wo ọjà kan ní Lọndọn tí àwọn èèyàn wá ń ná (àwọn àwòrán nísàlè)

Ìjọba UK ni láìpẹ́, ẹnikẹ́ni láti àwọn orílẹ̀èdè mélòókan, pẹ̀lú Naijiria, tó bá fẹ́ bẹ ilẹ̀ àwọn wò, ó ní láti fí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta pọ́ùn (₦750,000) lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdánilójú pé enítọ̀hún yó padà sílé tí ọjọ́ bá pé. Wọ́n ní tí ẹni náà bá padà, àwọn yó dá owó rẹ̀ padà fún un. Àmọ́ tí ó bá tayọ ọjọ́ kan péré, owó ọ̀hún di ọ̀lẹ̀lẹ̀ tó wọnú ẹ̀kọ nìyẹn.

Ṣé wọ́n ni bí kò bá ní ìdí obìnrin kìí jẹ́ Kúmólú. Àwọn òṣèlú UK fi yé aráyé pé àwọn ọmọ orílẹ̀èdè tí àwọn kà sílẹ̀ nì, wọn kò kí ń ṣábàá fẹ́ padà sílé lẹ́hìn tí àkókò tí a fún wọn ba tán. Gbogbo ènìyàn tí ọ̀rọ̀ yìí bà ké gbànjarè. Wọ́n ní ẹlẹ́yàmẹ̀yà ni ìjọba UK fi ṣe. Nítorí láàrin gbogbo àwọn orílẹ̀èdè tí wọ́n bá wí, kò sí ilẹ̀ aláwọ̀ funfun kankan níbẹ̀. Kíá ni ìjọba Naija náà fọhùn. Wọ́n rán UK létí pé òkò tí a sọ sí igi ọ̀pẹ ni í sọ padà sí ẹni. Kò bá rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́ ni a ò bá yọ̀ pé orí àwọn olórí wa náà ti ń pé bọ̀. Ẹ jẹ́ n mẹ́nu kúro ní bẹ̀un jàre.

Ní tèmi o, mo lérò pé ó yẹ ki àwọn oníṣòwò wa yé ná UK lemọ́-lemọ́. Ẹ jẹ́ kí àwa ilẹ̀ Afirika bá arawa ṣòwò, kí a máa ra ọjà arawa kí ìlọsiwájú tó péye lè dé bá wa. Kí a yé kó gbogbo owó wa wá sí òkè òkun níbi tí wọ́n ti ń yàn wá jẹ káàkiri, tí wọ́n tún ń fi ẹ̀gbin lọ̀ wá. Ẹ jẹ́ kí a yé fi ojú tẹ́mbẹ́lú nkan tiwa n'tiwa. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, irú ẹ̀gbìn yìí ò ní káwọ́ nílẹ̀ bọ̀rọ̀.

Ewu ńlá ńbẹ nínú epo-rọ̀bì!

Lẹ́nu òní sí àná ni a gbọ́ pé iná jó àwọn agbègbè kan ní ìlú Èkó. Ní Èbúté Mẹ́ta, àwọn agbẹ́gità, àwọn oníṣòwò pákó àti àwọn ìran apẹja ni iná nlá kan tó jó lánàá ṣe ní jàmbá. Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n ngbé ní abúlé kan tí wọ́n tẹ̀dó sórí omi ọ̀sà ní Èbúté Mẹ́ta. Nkan tó tún ṣeni láàánú ni pé tálíkà paraku ni gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ́. Oun ìní díẹ̀ tí wọ́n tún ni, àti iṣẹ́-òòjọ́ wọn náà sì ni wọ́n ti bá iná lọ.

Kìí ṣe àkọ́kọ́ rèé ni Nàaìjíríà o. Àìmọye irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló nṣẹlẹ̀ káàkiri orílẹ̀ wa. Kí ọkọ̀ méjì má tíì kọlu arawọn làá ti gbọ́ pé wọ́n gbiná wọ́n sì jóná ráú-ráú lójú òpópónà. Kí ló wá fàá? Ìbéèrè yìí ò sòro dáhùn o. Ìdí abájọ ni pé nítorí kòsí ètò ìtanná tó péye ní Naija, nṣe ni olúkálukú nlo ẹ̀rọ amúnáwá fi ṣe ìtanná fúnrarẹ̀. Nkan tí ẹ̀rọ yìí nlò ṣiṣẹ́ sì ni epo-rọ̀bì. Ajẹ́ pé àwọn ènìyàn nra epo pamọ́ silé. Ẹlòmíràn lè gbé odindi garawa epo sílé!

Ìdí míràn tí àwọn èèyàn ṣe máa ngbé adúrú epo báyìí sílé ni pé wọn kò mọ ìgbà tí epo lè tán ní ilé-epo, tí wọ́n sì máa láti ràá lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n ntún un tà lówó iyebíye ìlọ́po méjì tàbí mẹ́ta! Tí epo bá ti wà, wọ́n á yáa rọ gbogbo ọkọ̀ àti garawa wọn kún dẹ́mú-dẹ́mú. A jẹ́ pé gbogbo àwọn agbolé ní ìlú Èkó, àti ní gbogbo Nàìjíríà lápapọ̀, kìkì epo-rọ̀bì ni. Àb'ẹ́ẹ̀ rí ewu nlá bí? Njẹ́ ó yẹ́ kí ọmọ ènìyàn máa gbé irú ìlú báyìí?

Dájú-dájú ẹ̀bi ìjọba wa ni ọ̀rọ̀ yìí jẹ́. Ẹ̀kíní, tí wọ́n bá pèsè ètò-ìtanná to péye ni, àwọn èèyàn ò ní nílò àti máa gbé epo sílé rárá. Ẹ̀ẹ̀kejì, tí wọ́n bá pèsè epo-rọ̀bì tó káárí gbogbo gbòò, wọ́n á yéé gbé èpò sẹ́hìn ọkọ̀ rìn. Eléyìí á dẹ́kun ọkọ̀ gbígbiná lójú títì.

Àmọ́ àwọn ọmọ Naija náà kó díẹ̀ nínú ẹ̀bi o. Oríṣìíríṣìí ìkìlọ̀ ló ti bọ́ sí etí i wọn nípa ewu tí nbẹ nínú epo-rọ̀bì, ṣùgbọ́n ó dàbí ẹni pé bí ọ̀rọ̀ ọ̀hún ṣe ngba etí ọ̀tún wọlé ni ó ngba etí òsì jáde. Ẹni a wí fún, Ọba jẹ́ ó gbọ́. Èyí tí ò gbọ́ nṣe'rarẹ̀. Ó tó ṣe bí òwe.

Àwọn ọkọ̀ àti kẹ̀kẹ́ akérò ní Ìlú Èkó

Nkankan tó wùmí ní ìlú Èkó ni bí wọ́n ṣe kun gbogbo ọkọ̀ àti kẹ̀kẹ́ akérò ní ọ̀dà kannáà.  Èyí máà nmú kí gbogbo wọn bárawọn mu dáadáa kí wọ́n sì gúnrégé lójú, bíótilẹ̀jẹ́pé púpọ̀jù nínú wọn ti fẹ́ẹ̀ẹ́ bàjẹ́ tán.  Ó dàbí bí wọ́n ṣe kùn wọ́n náà ní ìlú New York ni.  Kì báà jẹ́ pé àwọn ọkọ̀ tiwọn tuntun nini yàtọ̀ sí tiwa 🙂

Ajíṣe bí Ọ̀yọ́ làá rí

Lónìí òpin ọdún 2012, tí a bá bojú wẹ̀hìn, a ó rí i pé ọ̀pọ̀ òjò ló ti rọ̀ lọ́dúnnìí, tí ilẹ̀ sì fi mu. Oríṣìíríṣìí nkan olókìkí ló ti ṣẹlẹ̀ ní Naijiria àti ni gbogbo àgbáyé. Àwọn nkan rere àti àwọn nkan búburú pẹ̀lú. Ọdún 2012 ni ìdíje Olympics wáyé ní ìlú Lọndon. Ọdún yìí náà ni wọ́n tún Obama yàn gẹ́gẹ́ bí ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹrika. Àwọn ìròhìn ayọ̀ oníkanòjọ̀kan náà la gbọ́ káàkiri àgbáyé.

Àmọ́ o, bí ó ti ntutù níbìkan ní í gbóná ní ibòmíràn. Àìmọye jàmbá la gbọ́ pé ó ṣelẹ̀ káàkiri àgbáyé lọ́dúnnìí. Ẹnìkan ló fi ikú ìbọn rán àwọn ọmọdé kékeré lọ sọ́run òjijì ní Amẹrika ni ìjọ́sí. Bẹ́ẹ̀náàni ààrẹ orílẹ̀ Síríà kò dáwọ́ pípa àwọm ọmọ ìlú rẹ̀ dúró. Àwọn ìjì nlá-nlá tún jà káàkiri àgbáyé, tí wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá lọ́. Ní Naija, ọkọ̀ òfurufú kò yéé jábọ́. Àwọn òlóṣèlú oníwàìbàjẹ́ ò yéé hùwà wọn. Àmọ́n èyí tó kanni lóminú jù ni ti àwọn alákatakítí Boko Haram, tí wọ́n ndúnbú ọmọ ènìyan bí eran lásán.

Ṣùgbọ́n ìrírí ayọ̀ ni tiwa ní ilẹ̀ Yorùbá ni ti ẹlẹ́sìn dé o. Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ẹlẹ́sìn Kiristẹ́nì àti Mùsùlùmí kìí bárawọn ṣe dáadáa ní gbogbo ibòmíràn, irẹ́pọ̀ gidi ló wà láàrin àwọn ẹlẹ́sìn méjéèjì ní ilẹ̀ Káàárọ̀-oòjíire. Kò ṣọ̀wọ́n ká rí ṣóòṣì àti mọ́ṣáláṣí tí wọ́n kọ́ si ẹ̀gbẹ́ arawọn. Ka rí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ to já èrò sílẹ̀, kí lágbájá kọrí sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ ké alelúyà, ki tẹ̀mẹ̀dù náà sì gba mọ́ṣáláṣí lọ rèé ké láìláà. Bó ti rí gẹ́lẹ́ ní ilẹ̀ Yoòbá nìyẹn láìsí ìjà, láìsí rògbòdìyàn.

Ní ọdún 2013 tó wọlé dé yìí, aríkọ́ṣe àti àwòkọ́ṣe ni ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ fún gbogbo àgbáyé nípa ìrẹ́pọ̀ èsìn. “Ajíṣe bí Ọ̀yọ́ làá rí o….” Kí gbogbo wa káàkiri àgbáyé jáwọ́ nínú ìwa ẹlẹ́sìnmẹ̀sìn tó nkó jambá nlá ba ilé-ayé yìí. Ọlọ́run níkan ló mọ ẹni tí ó là o.

Kẹ̀kẹ́ Marwa

 

Yàtọ̀ sí Ọkada tí í ṣe kẹ̀kẹ́ akérò alùpùpù ní Naija, kẹ̀kẹ́ Marwa – kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta ní í ṣe. Kẹ̀kẹ́ náà ti gbajú-gbajà ní ìlú Èkó àti awọn ìlu nlá-nlá kọ̀ọ̀kan káàkiri Naija. Lati orúkọ Mohammed Buba Marwa tí ó jẹ́ gómìnà Èkó nígbàkan ni orúkọ kẹ̀kẹ́ yìí ti jẹyọ.

Àwọn òpópónà àti títì kékeré nìkan ni òfin gba kẹ̀kẹ́ Marwa láàyè àti rìn. Ìdí ẹ̀ ni pé kò lágbára títì nlá rárá. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ nígbàtí akérò kan ṣàìgbọràn, tí ó ngbé èrò lọ lórí títì nlá tó lọ́ sí Ibadan láti Èkó. Ọkọ̀ akẹ́rù gbàngbà kan sáré kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Atẹ́gùn ọkọ̀ akẹ́rù náà lásán ló fẹ́ kẹ̀kẹ́ Marwa kúrò lójú títì tó fi forí sọ òpó kan, tí awakẹ̀kẹ́ àti àwọn èrò fi ara pa.

Nkan bí ọdún méjì sẹ́hìn ni mo ya àwòrán yìí ní àdúgbò Èbúté Mẹ́ta ní ìlú Èkó. Bíótilẹ̀jẹ́pé púpọ̀ nínú àwọn kẹ̀kẹ́ Marwa náà ti gbo ti wọ́n ti fẹ́ẹ̀ẹ́ bàjẹ́, tí wọ́n sì rí jáku-jàku, wọ́n kópa pàtàkì nínú ètò-ìrìnsẹ̀ àwọn ará ìlú, pàápàá jùlọ fún àwọn mẹ̀kúnù. Àti pé bí wọ́n ṣe kùn wọ́n ní ọ̀dà àláwọ̀ kánnáà jẹ́ kí wọ́n dùn-ún wò lójú. Ní èrò tèmi o, wọ́n bu ẹwà kún ìlú Èkó rẹpẹtẹ!

 

Iléyá ti dé

“♪…Iléya ti dé! Iléya ti dé! Iléya ti dé o, barika de Sallah ..♪”

Orin kan tí gbogbo àwọn ọmọdé máa nkọ ní ìlú wa nígbàtí mo wà ní kékeré nìyẹn. Tí ọdún iléya bá ti dé, gbogbo àwọn ọmọdé yálà Mùsùlùmí tàbí Onígbàgbọ́ Kìrìstẹ́nì ni, wọ́n a máa kọrin bẹ́ẹ̀.

Ní gbogbo àgbáyé, níbi tí a ti lè rí àwọn Mùsùlùmí àti Kìrìstẹ́nì tí wọ́n ngbé pọ̀ ní ìlú kannáà, kòsí ibi tí ìrẹ́pọ̀ wà tó ti ilẹ̀ Yorùbá! Ìdí abájọ ni pé ní ìdílé kan, a lè rí ẹnìkan tó jẹ́ Mùsùlùmí, kí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò onítọ̀hún jẹ́ Kìrìstẹ́nì. A rí mọ̀lẹ́bí ẹlẹ́sìn Ìgbàgbọ́ àti Mùsùlùmí ní agbolé kannáà nítorí wọ́n a máa fẹ́ arawọn láì sí ìkórira kankan. Àpẹrẹ rere ni èyí jẹ́ fún gbogbo àgbáyé. Pàápàá jùlọ fún àwọn ìlú tí àwọn ẹlẹ́sìn méjéèjì ti dojú ìjà ko arawọn. Àti fún àwọn aríwá orílẹ̀ Nàìjíríà lókè Ọya lọ́hùn-ún.

Ní ìlú tiwa ṣá o, àti Kìrìstẹ́nì o, àti Mùsùlùmí o, àti Abọ̀ìṣà o, àjọjẹ lẹran Iléyá!

Ẹkú ayájọ́ òmìnira Nàìjíríà

 
Ọjọ́ òní ló di ọdún méjìléláàádọ́ta báyìí tí Orílẹ̀ Nàìjíríà gba òmìnira lọ́wọ́ ìjọba amúnisìn ti ọba àwọn Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn ni wọ́n kó ilẹ̀ Yorùbá pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀yà míràn bíi àwọn Igbo àti Hausa sí orílẹ̀ kannáà, tí wọ́n sì sọ wá lórúkọ “Nigeria”.

Bíótilẹ̀jẹ́pé ànfàní mélòókan wà nínú bí wọ́n ṣe kó wa pọ̀ yìí, àlébù tí nbẹ́ níbẹ̀ kò níye. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ọjọ́ mìíì nìyẹn jẹ́.

Àkọsílẹ̀ tòní, ìkíni ló jẹ́. Ìkíni gbogbo ọmọ Nàìjíríà jákè-jádò nílé lóko lódò lẹ́hìn odi àti níbikíbi tó wù kí ẹ wà. Ẹkú ayájọ́ òmìnira orílẹ wa o.