Ilẹ̀-Ìyanu Ọ̀gìnìntìn

Ìgbésí ayé Alákọ̀wé apá kejì ti bọ́ o. Ẹ bá mi dé Ilẹ̀-Ìyanu Ọ̀gìnìntìn tí ń bẹ nínú ọgbà ńlá Hyde Park.

Ẹ má gbàgbé láti tẹ̀lé mi lórí YouTube o, kí n lè mọ̀n dájú pé ẹ ń gbádùn mi. Ṣé ẹ̀yin gbọ́rọ̀-gbọ́rọ̀ ni ọ̀gá àwa sọ̀rọ̀-sọ̀rọ̀.

Ẹṣeun púpọ̀ o.

Advertisements

Láìsí ìmọ́lẹ̀ kòsí àwòrán

Àsìkò òtútù ti wọlé dé tán, ilẹ̀ sì ti ń tètè ṣú lọ́dọ̀ wa níbí. Nígbà míì gan-an, tí òjò bá ṣú dẹdẹ láti òwúrọ̀ dé ìrọ̀lẹ́, á máa dàbí ẹni pé ilẹ̀ ò mọ́n rárá lọ́jọ́ náà ni. Ìdí ẹ̀ lèyí tó fi jẹ́ pé ọjọ́ tí oòrùn bá yọ, tí ojú-ọjọ́ bá fẹ́ ṣe bí ẹní mọ́n díẹ̀, kíà-kíà ni gbogbo wa má jáde síta láti gbádùn ìmọ́lẹ̀ àti lílọ́wọ́rọ́ oòrùn. Pàápàá àwa ayàwòrán, inú wa a máa dùn tí a bá ti rí irú ọjọ́ báyìí. Ńṣe la máa sáré bọ́ síta pẹ̀lú ẹ̀rọ ayàwòrán wa àti àwọn irinṣẹ́ rẹ̀.

Nkankan tó máa ń wuni púpọ̀ láti yà láwòrán ní àsìkò ìkórè tí a wà yìí ni àwọn ewéko àti àwọn igi. Àwọ̀ àwọn ewéko a máa jọ́ni lójú púpọ̀. Púpọ̀ nínú àwọn igi ni gbogbo ewé wọn ti rẹ̀ dà sílẹ̀ tán pátápátá. Àwọn igi míì tí wọ́n bá ti gbẹ á wọ́ lulẹ̀ tí ìjì kan bá jà, tàbí tí atẹ́gùn òjò tí ó lágbára bá fẹ́ lù wọ́n.

Díẹ̀ nínú àwọn àwòrán tí mo yà ní àárọ̀ yìí ni ìwọ̀nyí.

Ọgbà òdòdó

Ọgbà kan wà tí mo fẹ́ràn púpọ̀. Ọgbà òdòdó ni mo máa ń pè é. Kìí ṣe orúkọ rẹ̀ nìyẹn o, èmi ni mo sọ ọ́ lórúkọ bẹ́ẹ̀. ìdí ẹ̀ ni pé gbogbo ìgbà ni àwọn òdòdó aláràbarà máa ń wà nínú ọgbà náà. Kódà tí kìí bá ṣe àsìkò òdòdó rárá. A máa jẹ́ ìyàlẹ́nu fún gbogbo ẹni tó lọ síbẹ̀ nígbà tí kìí ṣe àsìkò tí àwọn òdòdó máa ń ṣábàá yọ.

Ṣé ọlá àbàtà ni í mú odò ṣàn. Ọlá àwọn onímọ̀jìnlẹ̀ ọ̀gbìn tí ikọ̀ wọn ń bẹ nínú ọgbà náà ni àwọn òdòdó náà ń jẹ. Àwọn ni wọ́n máa ń gbin àwọn òdòdó nì, tí wọ́n a ṣe ìtọ́jú àti ìmójútó wọn ní inú ikọ̀ wọn, tí wọ́n á sì gbìn wọ́n sí ìta gbangba inú ọgbà náà tí wọ́n bá ṣetán.

Ajẹ́pé t'òjò t'ọ̀gbẹlẹ̀ ni àwọn òdòdó ń tanná káàkiiri ọgbà náà. Tí wọ́n sì mú ọgbà náà wuni púpọ̀ púpọ̀.

 

Orí ọ̀kẹ́rẹ́ koko láwo

Orí ọ̀kẹ́rẹ́ koko láwo. Ẹ jẹ́ ká dàá'lẹ̀ ká tún un ṣà, ẹran jíjẹ ni ọ̀kẹ́rẹ́ jẹ́ ní ilẹ̀ Yorùbá. Pàápàá jùlọ tí èèyàn bá rí ọ̀kẹ́rẹ́ yíyan-gbẹ, tí wọ́n fi ata sí dáadáa, a máa dáni l'ọ́nàfun tòló. Èrò yí ló wá sọ́kàn mi ní ìjẹta tí mò ń ya àwòrán nínú ọgbà-ìtura kan ní Lọndọn. Ibẹ̀ ni mo ti ya àwòrán ọ̀kẹ́rẹ́ yìí.

Ẹ ṣàkíyèsí pé ńṣe ni mo súnmọ́ ọ tó báyìí, tí kò sì sálọ. Kódà, ọ̀kẹ́rẹ́ yìí nìkan kọ́ ni mo rí o. Wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ nínú ọgbà náà ni. Bí ọmọ ènìyàn ṣe ń gbafẹ́ ni àwọn náà ń gbádùn, láìsí ìbẹ̀rù-bojo kankan. Ìyanu ni èyí máa ń ṣábàá jẹ́ fún àwọn tí wọn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ìlú yìí, pàápàá jùlọ àwọn tí wọn ti ẹ̀bá ọ̀dọ̀ wa wá ní ilẹ̀ adúláwọ̀ tí ọ̀kẹ́rẹ́ ti í ṣe èròjà ọbẹ̀.

Ìdí abájọ ni pé 'ẹranko ìjọba' ni àwọn ọ̀kẹ́rẹ́ wọ̀nyí jẹ́. Wọ́n sì wà lábẹ́ àbò òfin orílẹ̀èdè yìí pẹ̀lú. Àti pé àwọn ará ìlú yìí ò kí ń fi irúfẹ́ ẹranko yìí ṣe oúnjẹ rárá. Dípò jíjẹ wọ́n, ńṣe ni àwọn èèyàn máa ń fi oúnjẹ lọ àwọn ọ̀kẹ́rẹ́ wọ̀nyí, tí wọ́n a sì máa bá wọn ṣeré. Nítorínáà àwọn ọ̀kẹ́rẹ́ náà mú ọ̀mọ̀ ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́, dípò nkan ẹ̀rù. Àwọn Gẹ̀ẹ́sì náà sì fẹ́ràn àwọn ẹranko tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, inú ilé ni ajá wọn máa ń ṣábàá bá wọn gbé.

Àmọ́ ní tèmi o, nígbàkígbà tí mo bá rí ọ̀kẹ́rẹ́, ibi tí wọ́n ti ń ta ẹran ìgbẹ́ yíyan-gbẹ ní Bódìjà ni ọkàn mi máa ń lọ.

Ọgbà ìfọ̀kànbalẹ̀

 

Àláfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ ṣe pàtàkìfún ìlera wa. Bíótilẹ̀jẹ́pé iṣẹ́ àti àwọn ojúṣe wa ò kí nṣábàá gbàwá láàyè láti dá àkókò ìsinmi sí lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ó ṣe kókó kí a gbìyànjú ẹ̀.

Ní tèmi o, mo máa nlọ sínú ọgbà kan nítòsí láti gba ìsinmi. Ọgbà yìí rẹwà púpọ̀ ó sì máa nṣábàá dákẹ́ rọ́rọ́. Ó ní adágún omi kan tí àwọn ẹja onírúirú wà, tí àwọn apẹjagbafẹ́ sì máa nwa jòkó sí etí ẹ̀.

Mo má nlo ọgbọ̀n ìṣẹ́jú sí wákàtí kan níbẹ̀. Àláfíà gbáà ni èyí jẹ́ fún mi. Ó sì tún fún mi ní àsìkò láti ronú jinlẹ̀ dáadáa. Mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ṣókí nínú móhùnmáwòrán tó wà lókè àkọslẹ̀ yìí.