Àjẹjù Ṣúgà ò dára fún Ènìyàn

Ajeju Suga

Ṣé mo sọ níjọ́sí pé ìfẹ́ àfẹ́jù tí ń bẹ láàrin ọmọ ènìyàn àti ṣúgà bímọ. Bẹ́ẹ̀ ni o. Kódà ọmọ tí wọ́n bí ju ẹyọ kan ṣoṣo lo. Àwọn ọmọ náà ni Ààrùn, Àìsàn, Àìlera àti Àárẹ̀.

Àwọn ọmọ wọ̀nyí a máa farahàn ní ìgbésí-ayé ẹ̀dá ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà àrà, wọn a sì máa da ọmọ-ènìyàn l’áàmú. Díẹ̀ nínú àwọn ọ̀nà àrà náà nìwọ̀nyí;

Ẹ̀jẹ̀ Ríru, Ìfúnpá Gíga, Ìtọ̀ Ṣúgà, Wárápá, Àìsàn Ọkàn, Ọpọlọ Wíwú, Ojú Fífọ́, Ìdákọ́lẹ, Àpọ̀jù Ọ̀rá-Ẹ̀jẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Abí ẹ kò rí i pé àjẹjù ṣúgà kò dára fún ọmọ ènìyàn rárá bí? Ó yẹ ká yẹra fún un nígbà gbogbo, kí ó má baà ṣe àkóbá fún wa.

Toò, ẹ jẹ́ ká fi man báhun lónìí nítorí pé “ṣókí l’ọbẹ̀ oge”. Èmi ni Alákọ̀wé yín ọ̀wọ́n. Ó tún dìgbà kan ná.

Advertisements

Omi

A kìí bómi ṣọ̀tá – ó ṣèwọ̀.

Ṣé omi làbùwẹ̀, òun làbùmu.

 

Jíjí tí mo jí ní kùtù-kùtù,

omi ni mo fi bọ́jú, òun ni mo fi fọnu.

 

Mo tọ orílẹ̀ yìí dé ìpẹ̀kun àríwá mo kan agbami

òkun àwòyó ni ń bẹ ní gúsù.

 

Njẹ́ orí rẹ làá tí tu'pọ́n

inú rẹ ni tọmọdé tàgbà ti ń játùbú.

 

Kòṣémánìí ni ọ́ omi

Ìwọ gan-an ni kòríkòsùn àrin òru

 

Orí rẹ ni Olódùmarè tẹ́ ilé-ayé lé

Ẹni fojú di ọ́, olúwarẹ̀ kàbùkù.

 

Ṣé ìwọ lọ̀ ń bẹ nínú ìtọ̀, ìwọ lọ̀ ń bẹ nínú itọ́

ìwọ ni omijé ti inú ẹyinjú

 

Orí mi má mà jẹ́ n pàdánù omi

Kòsí oun tí ń gbani lọ́wọ́ omi àfi ikú.

 

Etí òkun ìgbafẹ́

Oòrùn farahàn sí wa lópin ọ̀sẹ̀ yìí ní Ìlú Ọba. Bó bá ti rí báun ní ìlú èèbó wa níbí, eré-tete, ó di etí òkun. Àgàgà lọ́dúnnìí tí oòrùn fẹ́ ṣe àjèjì sí wa díẹ̀ ní ilẹ̀ yìí. Ẹni tí kò súnmọ́ etí òkun kankan lè wá adágún omi kan lọ, tàbí odò kan tí etí bèbè rẹ̀ tẹ́ pẹrẹsẹ tó sì ní ìyanrìn díẹ̀ tó ṣeé dùbúlẹ̀ sí. Tàbí kí wọ́n gbọ̀nà papa ìgbafẹ́ kan lọ. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ a máa wọ ọkọ̀ lọ sétí òkun bó ti wù kó jìnnà tó.

Àwọn ẹ̀dá a máa yáàrùn bí alángba, wọ́n a máa lúwẹ̀ẹ́ nínú omi òkun, wọ́n á máa súré ka pẹ̀lú ajá wọn. Òórùn ẹran sísùn a sì gbalẹ̀ bíi ti súyà. Ẹ lè tún máa gbọ́ àwọn orin aládùn níbìkọ̀ọ̀kan. Àwọn kan a máa ṣe eré-ìdárayá ọlọ́kanòjọ̀kan, bẹ́ẹ̀ àwọn míràn a bó sínú ọkọ̀ ojú omi. Ìdárayá gbáà ni oòrùn jẹ́ fún wa nílùú yìí o, ìlú òjò àti otútù.

 

Aláwàdà lórí okùn

Ẹ wo aláwàdà kan tí mo rí ní ìgboro London ní ìrọ̀lẹ́ àná.