Èkó

Ẹ ǹlẹ́ o ẹ̀yin ẹ̀dá Ọlọ́run wọ̀nyí. Fún apá kẹfà Ìgbésí-ayé Alákọ̀wé, ẹ fìkàlẹ̀ lé e pẹ̀lú mi nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yìí. Ẹ jẹ́ ká dé Ìpínlẹ̀ Èkó, ká wòran díẹ̀.

Ní gbogbo ìgbà, èmi a kúkú máa kan sáárá sí gómìnà Èkó àná – Alàgbà Raji Faṣọla. Iṣẹ́ ńlá ló ṣe. Àyípadà tó dé bá ìpínlẹ̀ yìí ò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn rárá. Ó sì sọ Èkó di ibi àmúyangan – ibi iyì, ibi ẹ̀yẹ.

Nígbà kan rí, èmi ò kí ń fẹ́ rìn tí ilẹ̀ bá ti ṣú. Àmọ́ lóde òní, ẹ̀rù ò ṣábà á ba’ni mọ́n. Ọpẹ́ ni f’Ólúwa fún àwọn àyípadà rere wọ̀nyí. A ò ní ri àpadà sí burúkú láí-láí o. Kí gómìnà òní yáa múra síṣẹ́ gidi-gaan ni.

Ẹ ò jẹ́ ká dánu dúró ń’bẹ̀un bí? Wọ́n ní “ọ̀rọ̀ púpọ̀, irọ́ ní í mú wá”. Yoòbá káàbọ̀. A jẹ́ pé mo kí gbogbo yín kú ọdún titun o. Ọdúnnìí, á sàn wá s’ówó, sàn wá s’ọ́mọ, sàn wá sí àláfíà – tí í ṣe baálẹ̀ ọrọ̀.

Àṣẹ.

Advertisements

Agbègbè Waterloo

Alákọ̀wé mo tún dé. Ní apá karùn-ún Ìgbésí-ayé Alákọ̀wé, ẹ jẹ́ ká yà sí agbègbè Waterloo, létí bèbè gúsù odò Thames, ní olú-ìlú Igilàńdì wa yìí. Ibi tí ọdún Kérésì ti ń lọ ni kẹlẹlẹ.

Agbègbè yìí la ti lè rí ọ̀bìrìkìtì ńlá tí wọ́n ń pè ní ‘ojú Lọndọn’ – London Eye.

London Eye tí wọ́n kọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì ẹ̀yẹ ọdún kẹgbẹ̀rúnkejì – ìyẹn ọdún márùndínlógún sẹ́yìn báyìí. Èròngbà àwọn t’ọ́n kọ́ ọ síbẹ̀ ni pé kó kàn wà níbẹ̀ fún bí ọdún kan sí méjì. Ṣùgbọ́n lónìí ó ti di bàbàrà, oun àtọ́kasí ní ilú Lọndọn o. Tí ẹ bá dé’bẹ̀ ẹ ó rí ìdí abájọ. Èro tó tò kalẹ̀ pé àwọn fẹ́ gùn ún ò l’óǹkà. Bẹ́ẹ̀ owó ni gbogbo wọn ó san, kìí ṣe ọ̀fẹ́.

Onírúirú àwọn òṣèré ni wọ́n máa ń ṣeré l’óde ibẹ̀. Láti káàkiri àgbáyé sì ni wọ́n ti wá. Kódà láti Afirika pẹ̀lú.

Oúnjẹ náà wà ní ọlọ́kanòjọ̀kan, bótilẹ̀jẹ́pé ìjẹkújẹ oní ṣúgà la rí jẹ lọ́jọ́ náà. Ńṣe ni sẹ́lẹ̀ru ṣọkọléètì ń ṣàn bí omi níbẹ̀.

Toò, a tún ṣe t’òní o, ọpẹ́ ni fún Olódùmarè. Ìyókù tun di ẹ̀yìn ọdún ńlá. Kí Olúwa ṣọ́ wa jù’gbà náà lọ o.

Ódàbọ̀.

Afárá Lọndọn

Pàtàkì ni afárá yìí jẹ́ ní Lọndọn. Àwọn ará Róòmù ni wọ́n kọ́kọ́ kọ́ afárá náà ní nkan bi 2,000 ọdún sẹ́yìn. Látìgbà náà, wọ́n ti tún un kọ́ lẹ́ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Ẹ bámi dé agbègbè àyíká Lọndọn Bridge – ìgbádùn ń bẹ níbẹ̀. Níbi ìgbádùn bá sì wà, dandan ni kí ẹ bá èmi kinní yìí níbẹ̀ 🙂

Mo kí yín kú ìpalẹ̀mọ́ ọdún o. Ire owó, ire ọmọ, ire àláfíà tí í ṣe baálẹ̀ ọrọ̀.

Ódìgbà kan ná.

Abúlé Stratford

Apá keta ti bà bí àdàbà o. Ẹ bámi dé abúlé kan ní Lọndọn tí wọ́n ń pè ní Stratford. Ibẹ̀ ni ìdíje Olympics ti ṣẹlẹ̀ ní ìdun-ùnta, ìyẹn l’ọ́dún mẹ́ta sẹ́yìn.

Ire o!

Ènìyàn àti Ṣúgà

Sibi Suga Yoruba
Yoòbá ò purọ́ nígbà tó wípé “a kìí fi oyin sẹ́nu ká tutọ́”. Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ni, ó sì nítumọ̀ púpọ̀. Àmọ́ bó ti nítumọ̀ ìjìnlẹ̀ náà ló ni ti eréfèé.

Àdídùn tí ń bẹ nínú oyin dára púpọ̀, ó sì kún nkan tí ara ẹni ń fẹ́. Ẹlẹ́dàá ló ṣe ètò oyin ṣíṣe, tí Ó sì fi fún kòkòrò abìyẹ́ nì láti máa ṣe.

Ní inú oje òdòdó ni kòkòrò oyin ti ń yọ àdídùn ṣe oyin. Nígbà tí mo wà ní kékeré, èmi àti ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi àti àwọn ọ̀rẹ́ wa máa ń fẹ́nu fa oje òdòdó mun. A máa dùn lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣé áńgẹ́lì ọmọdé ni kò jẹ́ ka pàdé èyí tó máa pa wá lára. Nígbà míràn gan-an ńṣe la máa kúkú sọ odidi òdòdó sẹ́nu kàló, tí a ó rún un lẹ́nu wọ̀mù-wọ̀mù, tí a ó sì gbé e mìn gbùn-ún, tí nkankan ò sì ní ṣe wá.

Ododo Yoruba
Bó ti wà láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé nìyẹn. Àwọn nkan tí Ẹlẹ́dàá ṣe, àwá ọmọ ènìyan pẹ̀lú, Ó ti fi ìbáṣepọ̀ sáàrin wa pé kí a jẹ́ aláànfàní arawa, kí a sì máa ṣe arawa lóore. Ìyẹn láàrin àwa ọmọ ènìyàn àti ẹranko gbogbo – ẹranko si ewéko, eweko sí ènìyàn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣùgbọ́n àwa ọmọ ènìyàn a kìí yé kọjá àyè wa. A ní ìrọwọ́-rọsẹ̀ tó ti wà láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àgbáyé yìí ò tẹ́ wa lọ́rùn o. A ní dandan àfi ká ṣe tí inú wa. A ní iṣẹ́ Ẹlẹ́dàá ò dára tó, àfi ká tún un ṣe ní ìlànà tiwa. Àpẹrẹ ìwà yìí kan rèé;

Ẹ̀dá ọmọ ènìyàn kọ̀ ó ní oyin ò dùn tó o. Ó tún wípe rárá, ìrèké náà kù díẹ̀ káàtó. A ní àfí ká ṣe ìwádìí nkan tó fa adùn inú àwọn nkan wọ̀nyí, kí a lè ṣe wọ́n ní ìlànà tiwa.

Ọmọ ènìyàn bá fún omi inú ìrèké, ó gbé e raná ti omi náa fi gbẹ, tí ó fi ku kiní kan funfun báláhú. Kiní ọ̀hún jọ iyọ̀, àmọ́ dídùn rẹ̀ yàtọ̀ sí ti iyọ̀, ó jọ ti oyin àti ìrèké. Ẹ̀dá ọmọ ènìyàn ní “Kò tán bí!? A ti rí ìdí abájọ, ojú ti ẹ̀yin ọmọ kòkòrò!”.

Kokoro Oyin Cocacola Yoruba

Ọmọ ènìyàn wo kiní ọ̀hún títí ó ní “Ṣúgà la ó máa pè ọ́”

Ṣúgà amáyé dùn
Ìwọ ni gan-an ajẹmáleètu
Àdídù inú oyin abara funfun
Àní ìwọ gan-an lọ dùn jù
Ìwọ ni ìrèké gbóríyìn fún
Àwọ̀ àlà rẹ ń wọ̀ mí lójú

Kofi Yoruba Suga

Láti ìgbà yìí ni ọmọ èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ń tọ́ kiní funfun ọ̀hún sí gbogbo nkan jíjẹ àti mímu. Wọn a máa tọ́ ṣúgà sí omi. Wọn a máa tọ́ ọ sí ẹ̀kọ mímu. Kódà àwọn kan a máa lá a ní gbẹrẹfu.

Àwọn àgbàlagbà Yorùbá ti parí ọ̀rọ̀ tipẹ́-tipẹ́. Wọ́n ní “Àṣejù ni bábá àṣetẹ́”. Ọ̀rọ̀ àgbà rèé, kì báà pẹ́, a máa padà ṣẹ nígbẹ̀yìn ni. Nígbà tó yá, ifẹ́ àfẹ́jù tí ń bẹ láàrin ọmọ ènìyàn àti ṣúgà bá bímọ. Ìfẹ́ ọ̀hún ni àṣejù. Ọmọ náà ni àṣetẹ́.

Kí wá ló ṣẹlẹ̀? N ó fi tó o yín létí láìpẹ́. Ẹ padà wá gbọ́ àbọ̀ ọ̀rọ̀.

Ẹ ṣeun, mò ń bọ̀ ná.

Pàtàkì Ìwé Kíkọ Àti Kíkà Ní Èdè Abínibí

Ogboju-ode-ninu-igbo-irunmole
Oun tí a ní là ń náání. Àwọn àgbà Yorùbá ni wọ́n wí bẹ́ẹ̀. Njẹ́ ní òde òni àwa ọmọ Odùduwà ń náání oun tiwa bí? Ọ̀rọ̀ ọ́ pọ̀ níbẹ̀ o ẹ̀yin ará mi. Ó dáa ẹ jẹ́ ká mú’kan níbẹ̀ ká gbé e yẹ̀wò.

Bíótilẹ̀jẹ́pé ọ̀pọ̀ ni kò fẹ́ràn láti máa sọ èdè Yorùbá lẹ́nu mọ́n, dájú-dájú púpọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí gbọ́ ọ l’ágbọ̀ọ́yé, wọn kò kàn kí ń sọ ọ́ ni.

Lára àwọn agbọ́másọ wọ̀nyí, bóyá la lè rí ìkankan nínú wọn tó mọn èdè Yorùbá kà dáradára, ká tilẹ̀ má sọ̀rọ̀ ọ kíkọ. Àgàgà tí a bá fi àmì sọ́rọ̀, a máa fa ìrújú fún púpọ̀ nínú wọn. Ó mú mi rántí nkan tí ẹnìkan wí lóri Twitter níjọ́sí. Ó ní Yorùbá kíkọ̀ èmi Alákọ̀wé fẹ́ jọ èdè Lárúbáwá lójú òun nítorí àwọn àmì ọ̀rọ̀ tí mo máa ń fi sí i. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún pa mí ní ẹ̀rin lọ́jọ́ náà kì í ṣe díẹ̀.

Àmọ́ ọ̀rọ̀ burúkú òhun ẹ̀rín kọ́ rèé ni ẹ̀yin èèyàn mi? À á ti wá gbọ́? Ṣé ẹ rí ibi tí ọmọ Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí nípà èdè Gẹ̀ẹ́sì kíkọ? Ótì o! Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀. Àbí ẹ rí ibi tí ọmọ Ilẹ̀ Faransé ti ń ránmú sọ Faransé bí? Èmi ò rí i rí o.

Ogboju-Ode
Kí ló wá fà á? Ìkíní ni pé l’óòótọ́ a kò ní ètò ìkọ̀wésílẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá kí àwọn Lárúbáwá àti àwọn ará Úróòpù tó dé. Ajẹ́pé kò sí nínú àṣà wa láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Àtẹnudẹ́nu àtìrandéran ni àwá ń ṣe ní àtètèkọ́ṣe. Ṣùgbọ́n ayé àtijọ́ nìyẹn o. Ayé ń lọ, à ń tọ̀ ọ́ ni. Èdè Yorùbá ti di kíkọsílẹ̀ ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn aṣíwájú èdè káàkiri Afirika nípa kíkọsílẹ̀.

Ìkejì ni pé àwa ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ Káàárọ̀oòjíire ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ pátápátá. Kódà, àfi bí ẹni pé ẹlòmíràn kórira èdè abínibí tirẹ̀ gan-an ni. Nítorí ìdí èyí a kì í ṣe àmúlò èdè Yorùbá fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ile-ìwé wa, tàbí fún ìjírórò l’áwùjọ òṣèlú, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Yorùbá ń parun lọ kọ́ yìí? Àbí kí ni ọ̀nà àbáyọ? Àwọ̀n àgbà Gẹ̀ẹ́sì bọ̀ wọ́n ní “Ìrìnàjò ńlá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbésẹ̀ kan ṣoṣo”. Gẹ̀ẹ́sì káàbọ̀ o jàre. Ọgbọ́n àgbà ń bẹ lọ́dọ̀ tiwọn náà. Ajẹ́pé Yoòbá gbọ́n Èèbó gbọ́n ni wọ́n fi dá ilẹ̀ London 🙂

Yoruba-Twitter
Ká tiẹ̀ pa àwàdà tì. Kíni irúfẹ́ ìgbésẹ̀ kíní tó bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò ńlá ìsọ́jí èdè Yorùbá kíkọ àti kíkà? Toò, ìyẹn dọwọ́ olúkúlùkù wa. Láyé òde òní gbogbo wa ni ònkọ̀wé níwọ̀n ara tiwa. Yálà lórí ẹ̀rọ ojútáyé nì tí a mọ̀n sí Facebook, tàbí àwùjọ ẹjọ́wẹ́wẹ́ nì tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Twitter. Kíní ṣe tí àwa ò máa ṣe àmúlò èdè wa lórí àwọn àwùjọ wọ̀nyí déédé. Lóòótọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì ló pabambarì káàkiri àgbàyé, àmọ́ a láti gbé èdè tiwa náà lárugẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ibòmíràn ṣe máa ń ṣe.

Toò, ọ̀rọ̀ mi ò jù báyìí lọ. Ṣé wọ́n ní “ọ̀rọ̀ púpọ̀, irọ́ ní í mú wá” Tó tó ṣe bí òwe. Ìpàdé wa bí oyin o.

#TweetYoruba

20140301-130230.jpg

Ẹ darapọ̀ mọ́n wa lórí Twitter lónìí fún ìgbélárugẹ èdè Yorùbá.

Àjọ̀dún #YAF

Ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá, ìyẹn Àbámẹ́ta àti Àìkú ọjọ́ 27 àti 28 oṣù yí, gọngọ sọ ní agbègbè Hackney. Ayẹyẹ àṣà ọnà Yorùbá ló ṣẹlẹ̀ ní ọgbà Clissold fún ọjọ́ méjì gbáko. Ọdún kẹẹ̀rin tí àjọ̀dún náà ṣẹlẹ̀ rèé. Wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ fún àjọyọ̀ gbogbo ọmọ káàárọ̀-oòjíire ni, àti àwọn ti ibi tí àṣà wa tàn dé káàkiri àgbáyé bíi Brasil àti Kuba.

Ọrísìírírìí ni wọ́n ṣe létò, àmọ́ èyí tó pabambarì ni Batala tí í ṣe ẹgbẹ́ onílù. Orílẹ̀èdè Ígílándì ni wọ́n ti wá àmọ́ irúfẹ́ ìlù tí wọ́n lù, Brasil ni àṣà ọ̀hún ti jẹyọ.

N kò bá kọ jù báyìí lọ, àmọ́ kíní ọ̀hún ò tiẹ̀ wúni lórí lọ títí o jàre. Àwọn olóòtú ètò gbìyàjú pé kí ayẹyẹ ọ̀hún ó l'árinrin, àmọ́ àwọn èèyàn wa ò kọbiara sí i. Bótilẹ̀jẹ́pé àwọn èèyàn wa tí wọ́n fi ìlú Lọndọn ṣe ibùgbé pọ̀ bí ilẹ̀ bí ẹní, pàápàá ní agbègbè Hackney gan-an, àwọn ọmọ Yoòbá tó yọjú síbẹ̀ lè má ju mẹ́wàá lọ. Ṣé ẹ mọ̀ pé nkan tiwa ò kí ń jọ wá lójú lọ lo títí. Kání òṣèré Amẹ́ríkà kan ló yọjú sí agbègbè náà báun, ọgbà náà ò bá kún dẹ́mú-dẹ́mú ni. Kí Edùmàrè ko wa yọ.

Nkan kejì tó kù díẹ̀ káàtó ni pé àwọn àwo orin tí wọ́n lù, àsán azonto ni. Èmi ò fi etí mi gbọ́ orin Yoòbá ẹyọkan ṣoṣo níbẹ̀ o. Kí ló dé? Yoòbá ni ọba ìlù, àwa ni ọba gbogbo orin.

Ìgbà tó ṣe díẹ̀ ni òjò bá bẹ̀rẹ̀, tí àrá ń sán fààràrà. Èmi lérò pé bóyá Olúkòso ń bínú ni. Àrẹ̀mú ò gbọ́ ìlù bàtá kankan, ló bá rọ̀jò lé kiní ọ̀hún jàre. Ni olúkálukú wá sá bọ́ sábẹ́ àwọn ìsọ̀ olónjẹ.

Mo jẹ súyà. Mo jẹ àsáró. Mo tún fi omi tútù lé e. Mo rìn káàkiri àwọn ìsọ̀ aláṣọ kọ̀ọ̀kan. Ìgbà tó yá tó dàbí ẹni pé wọn fẹ́ fi azonto di olúwarẹ̀ létí, ni mo bá kọrí'lé ní tèmi o jàre. Ìyókù tún di ọdún tí ń bọ̀, kí Ẹlẹ́mìí ó má gbà á.

 

Alakowe.com Pààrọ̀ ẹ̀wù

Ẹ pẹ̀lẹ́ o ẹ̀yin èèyàn mi.  Ó mà tó’jọ́ mẹ́ta kan tí mo ti kọ nkan síbí.  Àṣá ò pẹ́ lóko bẹ́ẹ̀ rí o, ọ̀nà ló jìn. Ṣẹ́ẹ̀ bínú?

Pèrègún tí ń bẹ lódò kìí kú. Ọdọọdún ló ń yọ àwọ̀ tuntun.  A díá fún alakowe.com tó pààrọ̀ ẹ̀wù. Bẹ́ẹ̀ ni o, a ti pa aṣọ aláwọ̀-ewé èsí tì, a gbé aṣọ àlà funfun báláú bọra.  
Ṣé ó wuyì àbí kò wuyì? Ó dára àbí kò dára?  Ẹ jẹ́ kí n gbọ́ o 🙂

Àyípadà míràn ni pé màá máa fi àwọn àwòrán tí mo ń yà hàn níbí.  Ṣé mo ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ayàwòrán ni mí. Òwe Gẹ̀ẹ́sì kan a sì máa wí pé àwòrán kan ṣoṣo a máa fọ ẹgbẹ̀rún gbólóhùn.  Òótọ́ ọ̀rọ̀ ni.

Toò, wọ́n ní oun tó bá yá kìí tún pẹ́. Ẹgbà’yí ẹ tọ́ ọ wò.  Ìlú Èkó rèé arómisá lẹ̀gbẹ-lẹ̀gbẹ.

Image

ImageImage

Yorùbá101

Yorùbá rẹwà l'édè. Ó dùn-ún sọ l'ẹ́nu, ó sì dùn-ún gbọ́ l'étí. Nínú ọrin kíkọ, ewì kíké tàbí òwe pípa, èdè Yorùbá ò l'ẹ́gbẹ́ ńbìkankan. Èdè tó kún fún àṣà tó wuyì tó sì jọjú ni Yorùbá ń ṣe. Ìdí ẹ̀ rèé tó fi ṣeni láàánú nígbàtí àwọn onímọ̀ fi yé wa pé tí a kò bá ṣọ́ra, èdè ńlá yìí á di nkan ìgbàgbé láàrin ọgọ́rùn-ún ọdún. Á wá di nkan ìtàn tí a ń tọ́ka sí láti òkèrè pé àwọn kan sọ èdè náà l'áyé àtijọ́.

Oríṣìíríṣìí ìdí ló fà á tí èdè Yorùbá ṣe ń jíjó àjórẹ̀hìn báyìí. N kò ní mẹ́nu ba gbogbo wọn, àmọ́ ọ̀kan ni pé àwọn ọmọ tí à ń bí l'óde òní ò kí ń ṣábàá gbọ́ Yorùbá mọ́. Yálà nítorí pé a bí wọn sí ìdálẹ̀ níbi tí wọn kò ti ń sọ Yoòbá ni, tàbí àwọn òbí ọmọ kò fi kọ́ wọn.

Ìdíkídìí tí kì báà jẹ́, àwọn ojúlówó ọmọ Yóòbá kọ̀ọ̀kan ti dìde káàkiri ilẹ̀ wa, àti káàkiri àgbáyé láti rí i pé èdè yìí kò parun, kò sì di nkan ìgbàgbé. Wọn ń ṣe akitiyan ní ọlọ́kanòjọ̀kan ní ọ̀ná tí wọ́n ní agbára láti ṣe àlátìlẹ́hìn fún èdè ilẹ̀ baba wọn.

Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Oòduà wọ̀nyí ni ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Olùkọ́ Àṣà. Àwọn ni wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá lórí iPad, Android ati ẹ̀rọ Ayárabíàṣá. “Yoruba101” ni wọ́n pè é, ó sì wà fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, papàá fún àwọn ọmọdé. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn nínú àwòrán lókè, Yorùbá pọ́mbélé ni olùkọ́ yìí jẹ́. Ó dé fìlà abetíajá sórí, ó wọ ìlẹ̀kẹ̀ iyùn sọ́rùn. Bíótilẹ̀jẹ́pé ẹlẹ́rìn-ín ẹ̀yẹ ni ọ̀gá-tíṣà yìí jẹ́, kò gba àrífín láàyè rárá o! Ẹgba ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ fún aláìgbọràn ọmọ gbogbo, gẹ́gẹ́ bí àṣà wa ní'lẹ̀ káàárọ̀-oòjíire.

Àwọn ètò ìdáni lẹ́kọ̀ọ́ míràn náà wà lọ́rí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé wọ̀nyí o, àmọ́ nkan tí Yorùbá101 tún fi yàtọ̀ ni lílo “ìṣiré”. Èyí á mú kí àwọn ọmọdé fẹ́ràn láti máa lò ó gan-an, kí wọ́n sì máa rántí ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ́ wọn dáradára. Nítorí àwọn ọmọdé fẹ́ràn eré ṣíṣe, gbogbo ọkàn àtí ọpọlọ wọ́n ní wọ́n máa ń kọ sí i.

Èrò tèmi ni pé, nípa ìdánilẹ́kọ̀ọ́ èdè tó yànjú, ètò yìí kù díẹ̀ níbìkọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n ó dámi lójú pé Olùkọ́ Àṣà ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò ni. “Ótúnkù” ni ìbọn ń ró, l'áṣà àwọn àgbà. Ẹ jẹ́ ká darapọ̀ mọ́n Olùkọ́ Àṣà, kí a báwọn gbé iṣẹ́ ọpọlọ wọn lárugẹ, kí a gbìmọ̀pọ̀ ṣe alátìlẹ́hìn fún ìlọsíwájú èdè àti àṣà ilẹ̀ wa.

Ẹ tẹ̀lé Olùkọ́ Àṣà lórí Twitter –> @Genii_Games

Fún iPad –> Yorùbá101